Joh 11:55-57
Joh 11:55-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé: ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́. Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jesu, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹmpili, wí pé, “kín ni ẹyin ti rò ó sí pé kì yóò wá sí àjọ?” Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.
Joh 11:55-57 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́. Nigbana ni nwọn nwá Jesu, nwọn si mba ara wọ́n sọ, bi nwọn ti duro ni tẹmpili, wipe, Ẹnyin ti rò o si? pe kì yio wá si ajọ? Njẹ awọn olori alufa ati awọn Farisi ti paṣẹ pe bi ẹnikan ba mọ̀ ibi ti o gbé wà, ki o fi i hàn, ki nwọn ki o le mu u.

Joh 11:55-57 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ti àwọn Juu, ọ̀pọ̀ eniyan gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti ìgbèríko, kí ó tó tó àkókò àjọ̀dún, kí wọ́n lè ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àjọ̀dún náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Jesu, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti dúró ninu Tẹmpili pé, “Kí ni ẹ rò? Ǹjẹ́ ó jẹ́ wá sí àjọ̀dún yìí?” Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.