Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye. Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀. Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu. On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀. On kì iṣe imọlẹ̀ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na. Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye. On si wà li aiye, nipasẹ rẹ̀ li a si ti da aiye, aiye kò si mọ̀ ọ. O tọ̀ awọn tirẹ̀ wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà a. Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́
Kà Joh 1
Feti si Joh 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 1:4-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò