Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé. Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀. Ọkunrin kan wà tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johanu. Òun ni ó wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kí ó lè jẹ́rìí sí ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo eniyan lè torí ẹ̀rí rẹ̀ gbàgbọ́. Kì í ṣe òun ni ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn ó wá láti jẹ́rìí ìmọ́lẹ̀ náà. Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé. Ọ̀rọ̀ ti wà ninu ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ayé, sibẹ ayé kò mọ̀ ọ́n. Ó wá sí ìlú ara rẹ̀, ṣugbọn àwọn ará ilé rẹ̀ kò gbà á. Ṣugbọn iye àwọn tí ó gbà á, ni ó fi àṣẹ fún láti di ọmọ Ọlọrun, àní àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.
Kà JOHANU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 1:4-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò