Jer 44
44
Wọ́n Pa Gedalaya
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá fun gbogbo awọn ara Juda ti ngbe ilẹ Egipti, ti ngbe Migdoli, ati Tafanesi, ati Nofu, ati ilẹ Patrosi, wipe,
2Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, ẹnyin ti ri gbogbo ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ati sori gbogbo ilu Juda; si wò o, ahoro ni nwọn li oni yi, ẹnikan kò si gbe inu wọn.
3Nitori ìwa-buburu wọn ti nwọn ti hú lati mu mi binu, ni lilọ lati sun turari ati lati sìn awọn ọlọrun miran, ti nwọn kò mọ̀, awọn, tabi ẹnyin, tabi awọn baba nyin.
4Emi si ran gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, emi dide ni kutukutu, mo rán wọn, wipe, A! ẹ máṣe ohun irira yi ti emi korira.
5Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ lati yipada kuro ninu ìwa-buburu wọn, ki nwọn ki o má sun turari fun ọlọrun miran.
6Nitorina ni mo ṣe dà ìrunu mi ati ibinu mi jade, a si daná rẹ̀ ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nwọn si di ofo ati ahoro, gẹgẹ bi ti oni yi.
7Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, nitori kini ẹ ṣe da ẹ̀ṣẹ nla yi si ọkàn nyin, lati ke ninu nyin ani ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati ọmọ-ọmu, kuro lãrin Juda, lati má kù iyokú fun nyin;
8Ninu eyiti ẹnyin fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, ni sisun turari fun ọlọrun miran ni ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin lọ lati ṣatipo, ki ẹ le ke ara nyin kuro, ati ki ẹ le jẹ ẹni-ègun ati ẹsin, lãrin gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye?
9Ẹnyin ha ti gbagbe ìwa-buburu awọn baba nyin, ati ìwa-buburu awọn ọba Juda, ati ìwa-buburu awọn aya wọn, ati ìwa-buburu ẹnyin tikara nyin, ati ìwa-buburu awọn aya nyin, ti nwọn ti hù ni ilẹ Juda, ati ni ita Jerusalemu.
10Nwọn kò rẹ̀ ara wọn silẹ titi di oni yi, bẹ̃ni wọn kò bẹ̀ru, tabi ki nwọn ki o rìn ninu ofin mi, tabi ninu ilana mi ti emi gbe kalẹ niwaju nyin ati niwaju awọn baba nyin.
11Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, wò o emi doju mi kọ nyin fun ibi, ati lati ke gbogbo Juda kuro.
12Emi o si mu gbogbo iyokù Juda, ti o ti gbe oju wọn si ati lọ si ilẹ Egipti, lati ṣatipo nibẹ, gbogbo wọn ni yio si run, nwọn o si ṣubu ni ilẹ Egipti; nwọn o si run nipa idà ati nipa ìyan, nwọn o kú lati ẹni-kekere wọn titi de ẹni-nla wọn, nipa idà, ati nipa ìyan: nwọn o si di ẹni-ègun, ẹni-iyanu, ati ẹni-ẹ̀gan, ati ẹsin.
13Nitori emi o bẹ̀ awọn ti ngbe Egipti wò, gẹgẹ bi emi ti jẹ Jerusalemu niya, nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-arun;
14Kì o si si ẹniti o sala, ati ẹniti o kù, fun awọn iyokù Juda, ti o wọ ilẹ Egipti lati ma ṣatipo nibẹ, ti yio pada si ilẹ Juda, si eyiti nwọn ni ifẹ ati pada lọ igbe ibẹ: nitori kò si ọkan ti yio pada bikoṣe iru awọn ti o sala.
15Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn mọ̀ daju pe, awọn aya wọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ati gbogbo awọn obinrin ti o duro nibẹ, apejọ nla, ati gbogbo awọn enia ti ngbe ilẹ Egipti ani ni Patrosi, da Jeremiah lohùn, wipe,
16Ọ̀rọ ti iwọ sọ fun wa li orukọ Oluwa, awa kì yio feti si tirẹ.
17Ṣugbọn dajudaju awa o ṣe ohunkohun ti o jade lati ẹnu wa wá, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, gẹgẹ bi awa ti ṣe, awa, ati awọn baba wa, awọn ọba wa, ati awọn ijoye wa ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nigbana awa ni onjẹ pupọ, a si ṣe rere, a kò si ri ibi.
18Ṣugbọn lati igba ti awa ti fi sisun turari fun ayaba ọrun silẹ, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, awa ti ṣalaini ohun gbogbo, a si run nipa idà ati nipa ìyan.
19Ati nigbati awa sun turari fun ayaba ọrun ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u, lẹhin awọn ọkọ wa ni awa ha dín akara didùn rẹ̀ lati bọ ọ, ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u bi?
20Nigbana ni Jeremiah sọ fun gbogbo awọn enia, fun awọn ọkunrin, ati fun awọn obinrin, ati fun gbogbo awọn enia ti o ti fun u li èsi yi wipe.
21Turari ti ẹnyin sun ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu, ẹnyin ati awọn baba nyin, awọn ọba nyin, ati awọn ijoye nyin, ati awọn enia ilẹ na, Oluwa kò ha ranti rẹ̀, kò ha si wá si ọkàn rẹ̀?
22Tobẹ̃ ti Oluwa kò le rọju pẹ mọ, nitori buburu iṣe nyin, ati nitori ohun irira ti ẹnyin ti ṣe; bẹ̃ni ilẹ nyin di ahoro, ati iyanu ati ègun, laini olugbe, bi o ti ri li oni yi.
23Nitori ti ẹnyin ti sun turari, ati nitori ti ẹnyin ṣẹ̀ si Oluwa, ti ẹnyin kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, ti ẹ kò rin ninu ofin rẹ̀, ati ninu ilana rẹ̀, ati ninu ọ̀rọ ẹri rẹ̀; nitorina ni ibi yi ṣe de si nyin, bi o ti ri li oni yi.
24Jeremiah sọ pẹlu fun gbogbo awọn enia, ati fun gbogbo awọn obinrin na pe, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa gbogbo Juda ti o wà ni ilẹ Egipti:
25Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli sọ, wipe, Ẹnyin ati awọn aya nyin, ẹnyin fi ẹnu nyin sọ̀rọ, ẹ si fi ọwọ nyin mu ṣẹ, ẹ si wipe, lõtọ awa o san ẹ̀jẹ́ wa ti awa ti jẹ, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, njẹ ni pipamọ, ẹ pa ẹ̀jẹ́ nyin mọ, ati ni sisan ẹ san ẹ̀jẹ́ nyin.
26Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo Juda ti ngbe ilẹ Egipti, sa wò o, emi ti fi orukọ nlanla mi bura, li Oluwa wi, pé, a kì yio pè orukọ mi li ẹnu ọkunrin-kunrin Juda ni gbogbo ilẹ Egipti, wipe, Oluwa, Ọlọrun wà.
27Wò o, emi o ṣọ wọn fun ibi, kì si iṣe fun rere: ati gbogbo awọn ọkunrin Juda ti o wà ni ilẹ Egipti ni a o run nipa idà, ati nipa ìyan, titi nwọn o fi tan.
28Ati awọn ti o sala lọwọ idà, yio pada ni iye diẹ lati ilẹ Egipti si ilẹ Juda; ati gbogbo iyokù Juda, ti o lọ si ilẹ Egipti lati ṣatipo nibẹ, yio mọ̀ ọ̀rọ tani yio duro, temi, tabi ti wọn.
29Eyi ni yio si jẹ àmi fun nyin, li Oluwa wi, pe, emi o jẹ nyin niya ni ibiyi, ki ẹnyin le mọ̀ pe: ọ̀rọ mi yio duro dajudaju si nyin fun ibi:
30Bayi li Oluwa wi; wò o, emi o fi Farao-hofra, ọba Egipti, le ọwọ awọn ọta rẹ̀, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi rẹ̀; gẹgẹ bi emi ti fi Sedekiah, ọba Juda, le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli ọta rẹ̀, ti o si wá ẹmi rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 44: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.