Jer 45

45
Ìlérí Ọlọrun fún Baruku
1Ọ̀RỌ ti Jeremiah, woli, sọ fun Baruku, ọmọ Neriah nigbati o ti kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwe tan li ẹnu Jeremiah li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe,
2Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi fun ọ, iwọ Baruku;
3Iwọ wipe, Egbé ni fun mi nisisiyi! nitori ti Oluwa ti fi ibanujẹ kún ikãnu mi; ãrẹ̀ mu mi ninu ẹ̀dun mi, emi kò si ri isimi.
4Bayi ni ki iwọ sọ fun u, Oluwa wi bayi; pe, Wò o, eyi ti emi ti kọ́, li emi o wo lulẹ, ati eyi ti emi ti gbìn li emi o fà tu, ani gbogbo ilẹ yi.
5Iwọ ha si mbere ohun nla fun ara rẹ? máṣe bere: nitori, wò o, emi o mu ibi wá sori gbogbo ẹran-ara, li Oluwa wi: ṣugbọn ẹmi rẹ li emi o fi fun ọ bi ikogun ni gbogbo ibiti iwọ ba lọ si.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 45: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀