Jer 2:11-13

Jer 2:11-13 YBCV

Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè. Ki ẹnu ki o ya ọrun nitori eyi, ki o si dãmu, ki o si di gbigbẹ, li Oluwa wi! Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.