Jer 2:11-13
Jer 2:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè. Ki ẹnu ki o ya ọrun nitori eyi, ki o si dãmu, ki o si di gbigbẹ, li Oluwa wi! Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.

Jer 2:11-13 Yoruba Bible (YCE)
Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́? Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn, wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀. Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run, kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.” OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji: wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀, wọ́n ṣe kànga fún ara wọn; kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró.
Jer 2:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Orílẹ̀-èdè kan ha á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà? (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run) àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì. Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni OLúWA wí. “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.