Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru loju OLUWA: OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israeli, nitoripe nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju OLUWA.
O si kó awọn ọmọ Ammoni ati ti Amaleki mọra rẹ̀; o si lọ o kọlù Israeli, nwọn si gbà ilu ọpẹ.
Awọn ọmọ Israeli si sìn Egloni ọba Moabu li ọdún mejidilogun.
Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn, Ehudu ọmọ Gera, ẹ̀ya Benjamini, ọlọwọ́-òsi: awọn ọmọ Israeli si fi ẹ̀bun rán a si Egloni ọba Moabu.
Ehudu si rọ idà kan olojumeji, igbọnwọ kan ni gigùn; on si sán a si abẹ aṣọ rẹ̀ ni itan ọtún.
O si mú ọrẹ na wá fun Egloni ọba Moabu; Egloni si jẹ́ ọkunrin ti o sanra pupọ̀.
Nigbati o si fi ọrẹ na fun u tán, o rán awọn enia ti o rù ọrẹ na pada lọ.
Ṣugbọn on tikara rẹ̀ pada lati ibi ere finfin ti o wà leti Gilgali, o si wipe, Ọba, mo lí ọ̀rọ ìkọkọ kan ibá ọ sọ. On si wipe, Ẹ dakẹ. Gbogbo awọn ẹniti o duro tì i si jade kuro lọdọ rẹ̀.
Ehudu si tọ̀ ọ wá; on si nikan joko ninu yará itura rẹ̀. Ehudu si wipe, Mo lí ọ̀rọ kan lati ọdọ Ọlọrun wá fun ọ. On si dide kuro ni ibujoko rẹ̀.
Ehudu si nà ọwọ́ òsi rẹ̀, o si yọ idà na kuro ni itan ọtún rẹ̀, o si fi gún u ni ikùn:
Ati idà ati ekù si wọle; ọrá si bò idà na nitoriti kò fà idà na yọ kuro ninu ikun rẹ̀; o si yọ lẹhin.
Nigbana ni Ehudu si ba ti iloro lọ, o si se ilẹkun gbọngan na mọ́ ọ, o si tì wọn.
Nigbati o si jade lọ tán, awọn iranṣẹ rẹ̀ dé; nigbati nwọn wò, si kiyesi i, awọn ilẹkun gbọngan tì; nwọn wipe, Li aisí aniani o bò ẹsẹ̀ rẹ̀ ninu yará itura rẹ̀.
Nwọn si duro titi o fi di itiju fun wọn: kiyesi i on kò si ṣí ilẹkun gbọngan na silẹ; nitorina nwọn mú ọmọlẹkun, nwọn si ṣí i: si kiyesi i, oluwa wọn ti ṣubu lulẹ kú.
Ehudu si sálọ nigbati nwọn nduro, o si kọja ibi ere finfin, o si sálọ si Seira.
O si ṣe, nigbati o dé, o fọn ipè ni ilẹ òke Efraimu, awọn ọmọ Israeli si bá a sọkalẹ lọ lati òke na wá, on si wà niwaju wọn.
On si wi fun wọn pe, Ẹ ma tọ̀ mi lẹhin: nitoriti OLUWA ti fi awọn ọtá nyin awọn ara Moabu lé nyin lọwọ. Nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ, nwọn si gbà ìwọdo Jordani, ti o wà ni ìha Moabu, nwọn kò si jẹ ki ẹnikan ki o kọja mọ̀.
Nwọn si pa ìwọn ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ara Moabu ni ìgba na, gbogbo awọn ti o sigbọnlẹ, ati gbogbo awọn akọni ọkunrin; kò sí ọkunrin kanṣoṣo ti o sálà.
Bẹ̃li a tẹ̀ ori Moabu ba ni ijọ́ na li abẹ ọwọ́ Israeli. Ilẹ na si simi li ọgọrin ọdún.