A. Oni 3

3
Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ó Ṣẹ́kù lórí Ilẹ̀ Kenaani
1NJẸ wọnyi li awọn orilẹ-ède ti OLUWA fisilẹ, lati ma fi wọn dan Israeli wò, ani iye awọn ti kò mọ̀ gbogbo ogun Kenaani;
2Nitori idí yi pe, ki iran awọn ọmọ Israeli ki o le mọ̀, lati ma kọ́ wọn li ogun, ani irú awọn ti kò ti mọ̀ ọ niṣaju rí;
3Awọn ijoye Filistini marun, ati gbogbo awọn Kenaani, ati awọn ara Sidoni, ati awọn Hifi ti ngbé òke Lebanoni, lati òke Baali-hermoni lọ dé atiwọ̀ Hamati.
4Wọnyi li a o si ma fi dan Israeli wò, lati mọ̀ bi nwọn o fetisi ofin OLUWA, ti o fi fun awọn baba wọn lati ọwọ́ Mose wá.
5Awọn ọmọ Israeli si joko lãrin awọn ara Kenaani; ati awọn Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi:
6Nwọn si fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, nwọn si fi awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọkunrin wọn, nwọn si nsìn awọn oriṣa wọn.
Otnieli
7Awọn ọmọ Israeli si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nwọn si gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, nwọn si nsìn Baalimu ati Aṣerotu.
8Nitori na ibinu OLUWA ru si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia: awọn ọmọ Israeli si sìn Kuṣani-riṣataimu li ọdún mẹjọ.
9Nigbati awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun awọn ọmọ Israeli, ẹniti o gbà wọn, ani Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu.
10Ẹmi OLUWA si wà lara rẹ̀, on si ṣe idajọ Israeli, o si jade ogun, OLUWA si fi Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọwọ: ọwọ́ rẹ̀ si bori Kuṣani-riṣataimu.
11Ilẹ na si simi li ogoji ọdún. Otnieli ọmọ Kenasi si kú.
Ehudu
12Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru loju OLUWA: OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israeli, nitoripe nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju OLUWA.
13O si kó awọn ọmọ Ammoni ati ti Amaleki mọra rẹ̀; o si lọ o kọlù Israeli, nwọn si gbà ilu ọpẹ.
14Awọn ọmọ Israeli si sìn Egloni ọba Moabu li ọdún mejidilogun.
15Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn, Ehudu ọmọ Gera, ẹ̀ya Benjamini, ọlọwọ́-òsi: awọn ọmọ Israeli si fi ẹ̀bun rán a si Egloni ọba Moabu.
16Ehudu si rọ idà kan olojumeji, igbọnwọ kan ni gigùn; on si sán a si abẹ aṣọ rẹ̀ ni itan ọtún.
17O si mú ọrẹ na wá fun Egloni ọba Moabu; Egloni si jẹ́ ọkunrin ti o sanra pupọ̀.
18Nigbati o si fi ọrẹ na fun u tán, o rán awọn enia ti o rù ọrẹ na pada lọ.
19Ṣugbọn on tikara rẹ̀ pada lati ibi ere finfin ti o wà leti Gilgali, o si wipe, Ọba, mo lí ọ̀rọ ìkọkọ kan ibá ọ sọ. On si wipe, Ẹ dakẹ. Gbogbo awọn ẹniti o duro tì i si jade kuro lọdọ rẹ̀.
20Ehudu si tọ̀ ọ wá; on si nikan joko ninu yará itura rẹ̀. Ehudu si wipe, Mo lí ọ̀rọ kan lati ọdọ Ọlọrun wá fun ọ. On si dide kuro ni ibujoko rẹ̀.
21Ehudu si nà ọwọ́ òsi rẹ̀, o si yọ idà na kuro ni itan ọtún rẹ̀, o si fi gún u ni ikùn:
22Ati idà ati ekù si wọle; ọrá si bò idà na nitoriti kò fà idà na yọ kuro ninu ikun rẹ̀; o si yọ lẹhin.
23Nigbana ni Ehudu si ba ti iloro lọ, o si se ilẹkun gbọngan na mọ́ ọ, o si tì wọn.
24Nigbati o si jade lọ tán, awọn iranṣẹ rẹ̀ dé; nigbati nwọn wò, si kiyesi i, awọn ilẹkun gbọngan tì; nwọn wipe, Li aisí aniani o bò ẹsẹ̀ rẹ̀ ninu yará itura rẹ̀.
25Nwọn si duro titi o fi di itiju fun wọn: kiyesi i on kò si ṣí ilẹkun gbọngan na silẹ; nitorina nwọn mú ọmọlẹkun, nwọn si ṣí i: si kiyesi i, oluwa wọn ti ṣubu lulẹ kú.
26Ehudu si sálọ nigbati nwọn nduro, o si kọja ibi ere finfin, o si sálọ si Seira.
27O si ṣe, nigbati o dé, o fọn ipè ni ilẹ òke Efraimu, awọn ọmọ Israeli si bá a sọkalẹ lọ lati òke na wá, on si wà niwaju wọn.
28On si wi fun wọn pe, Ẹ ma tọ̀ mi lẹhin: nitoriti OLUWA ti fi awọn ọtá nyin awọn ara Moabu lé nyin lọwọ. Nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ, nwọn si gbà ìwọdo Jordani, ti o wà ni ìha Moabu, nwọn kò si jẹ ki ẹnikan ki o kọja mọ̀.
29Nwọn si pa ìwọn ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ara Moabu ni ìgba na, gbogbo awọn ti o sigbọnlẹ, ati gbogbo awọn akọni ọkunrin; kò sí ọkunrin kanṣoṣo ti o sálà.
30Bẹ̃li a tẹ̀ ori Moabu ba ni ijọ́ na li abẹ ọwọ́ Israeli. Ilẹ na si simi li ọgọrin ọdún.
Ṣamgari
31Lẹhin rẹ̀ ni Ṣamgari ọmọ Anati, ẹniti o fi ọpá ti a fi ndà akọmalu pa ẹgbẹta ọkunrin ninu awọn ara Filistini, on pẹlu si gbà Israeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

A. Oni 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa