Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si. Iwọ ti mu orilẹ-ède nì bi si i pupọ̀pupọ̀, iwọ si sọ ayọ̀ di pupọ̀ fun u: nwọn nyọ̀ niwaju rẹ gẹgẹ bi ayọ̀ ikore, ati gẹgẹ bi enia iti yọ̀ nigbati nwọn npin ikogun. Nitori iwọ ṣẹ́ ajàga-irú rẹ̀, ati ọpá ejika rẹ̀, ọgọ aninilara rẹ̀, gẹgẹ bi li ọjọ Midiani. Nitori gbogbo ihamọra awọn ologun ninu irọkẹ̀kẹ, ati aṣọ ti a yi ninu ẹ̀jẹ, yio jẹ fun ijoná ati igi iná. Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia. Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.
Kà Isa 9
Feti si Isa 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 9:2-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò