Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri. Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà. Ó ti fi kún ayọ̀ wọn; wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè. Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun. Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn, ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká, ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n. Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani. Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun, ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun, iná yóo sì jó wọn run. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia. Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi. Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo, láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí
Kà AISAYA 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 9:2-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò