Isa 33:1-6

Isa 33:1-6 YBCV

EGBÉ ni fun iwọ abanijẹ, ti a kò si bà ọ jẹ: ti o nhùwa arekereke, ti a kò si hùwa arekereke si ọ! nigbati iwọ o dẹkun ati banijẹ, a o bà ọ jẹ; ati nigbati iwọ bá fi opin si ihùwa arekereke, nwọn o hùwa arekereke si ọ. Oluwa, ṣãnu fun wa; awa ti duro dè ọ: iwọ mã ṣe apá wọn li òròwúrọ̀ ani igbala wa nigba ipọnju. Li ariwo irọ́kẹ̀kẹ li awọn enia sá, ni gbigbe ara rẹ soke li a fọ́n awọn orilẹ-ède ká. A o si ṣà ikogun nyin jọ bi ikojọ awọn ẹlẹngà: bi isure siwa, isure sẹhìn awọn eṣú, li on o sure si wọn. Gbigbega li Oluwa; nitori on ngbe ibi giga: on ti fi idajọ ati ododo kún Sioni. On o si jẹ iduroṣinṣin akoko rẹ̀, iṣura igbala, ọgbọ́n ati ìmọ; ìbẹru Oluwa ni yio jẹ iṣura rẹ̀.