Isa 33:1-6
Isa 33:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
EGBÉ ni fun iwọ abanijẹ, ti a kò si bà ọ jẹ: ti o nhùwa arekereke, ti a kò si hùwa arekereke si ọ! nigbati iwọ o dẹkun ati banijẹ, a o bà ọ jẹ; ati nigbati iwọ bá fi opin si ihùwa arekereke, nwọn o hùwa arekereke si ọ. Oluwa, ṣãnu fun wa; awa ti duro dè ọ: iwọ mã ṣe apá wọn li òròwúrọ̀ ani igbala wa nigba ipọnju. Li ariwo irọ́kẹ̀kẹ li awọn enia sá, ni gbigbe ara rẹ soke li a fọ́n awọn orilẹ-ède ká. A o si ṣà ikogun nyin jọ bi ikojọ awọn ẹlẹngà: bi isure siwa, isure sẹhìn awọn eṣú, li on o sure si wọn. Gbigbega li Oluwa; nitori on ngbe ibi giga: on ti fi idajọ ati ododo kún Sioni. On o si jẹ iduroṣinṣin akoko rẹ̀, iṣura igbala, ọgbọ́n ati ìmọ; ìbẹru Oluwa ni yio jẹ iṣura rẹ̀.

Isa 33:1-6 Yoruba Bible (YCE)
O gbé! Ìwọ tí ń panirun, tí ẹnìkan kò parun, ìwọ tí ò ń hùwà ọ̀dàlẹ̀ nígbà tí ẹnìkan kò dà ọ́. Ìgbà tí o bá dáwọ́ ìpanirun dúró, nígbà náà ni a óo pa ìwọ gan-an run; nígbà tí o bá fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ sílẹ̀, nígbà náà ni a óo dà ọ́. Ṣàánú wa OLUWA, ìwọ ni a dúró tí à ń wò. Máa ràn wá lọ́wọ́ lojoojumọ, sì máa jẹ́ olùgbàlà wa nígbà ìṣòro. Àwọn orílẹ̀-èdè sá nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo tí ó dàbí ti ààrá, wọ́n fọ́n ká nígbà tí o gbéra nílẹ̀. A kó ìkógun jọ bí ìgbà tí tata bo oko, àwọn eniyan dà bo ìṣúra, bí ìgbà tí eṣú bo oko. A gbé OLUWA ga! Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé; yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni. Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀. Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀, ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀.
Isa 33:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun, ìwọ tí a kò tí ì parun! Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀, ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́! Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run; a ó pa ìwọ náà run, nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani, a ó da ìwọ náà. OLúWA ṣàánú fún wa àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ. Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú. Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká. Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀. A gbé OLúWA ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga; Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo. Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀; ìbẹ̀rù OLúWA ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.