Ara ile Jakobu, ẹ wá, ẹ jẹ́ ka rìn ninu imọlẹ Ọluwa. Nitorina ni iwọ ṣe kọ̀ awọn enia rẹ, ile Jakobu silẹ̀; nitoriti nwọn kún lati ìla ọ̀run wá, nwọn jẹ alafọ̀ṣẹ bi awọn ara Filistia, nwọn si nṣe inu didùn ninu awọn ọmọ alejò. Ilẹ wọn pẹlu kún fun fadakà ati wurà; bẹ̃ni kò si opin fun iṣura wọn; ilẹ wọn si kun fun ẹṣin, bẹ̃ni kò si opin fun kẹkẹ́ ogun wọn. Ilẹ wọn kún fun oriṣa pẹlu; nwọn mbọ iṣẹ ọwọ́ ara wọn, eyiti ika awọn tikalawọn ti ṣe. Enia lasan si foribalẹ, ẹni-nla si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; nitorina má ṣe darijì wọn. Wọ̀ inu apata lọ, ki o si fi ara rẹ pamọ ninu ekuru, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀. A o rẹ̀ ìwo giga enia silẹ, a o si tẹ̀ ori igberaga enia ba, Oluwa nikanṣoṣo li a o gbe ga li ọjọ na.
Kà Isa 2
Feti si Isa 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 2:5-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò