NITORI Oluwa yio ṣãnu fun Jakobu, yio si tun yan Israeli, yio si mu wọn gbe ilẹ wọn; alejò yio si dapọ̀ mọ wọn, nwọn o si faramọ ile Jakobu.
Awọn enia yio si mu wọn, nwọn o si mu wọn wá si ipò wọn: ile Israeli yio si ni wọn ni ilẹ Oluwa, fun iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin: awọn ti o ti kó wọn ni igbekun ni nwọn o kó ni igbekun; nwọn o si ṣe akoso aninilara wọn.
Yio si ṣe li ọjọ ti Oluwa yio fun ọ ni isimi kuro ninu ibanujẹ rẹ, ati kuro ninu ijaiya rẹ, ati kuro ninu oko-ẹru lile nibiti a ti mu ọ sìn,
Ni iwọ o si fi ọba Babiloni ṣẹ̀fẹ yi, ti iwọ o si wipe, Aninilara nì ha ti ṣe dakẹ! alọnilọwọgbà wura dakẹ!
Oluwa ti ṣẹ ọpá oluṣe-buburu, ati ọpá-alade awọn alakoso.
Ẹniti o fi ibinu lù awọn enia lai dawọ duro, ẹniti o fi ibinu ṣe akoso awọn orilẹ-ède, li a nṣe inunibini si, lai dẹkun.
Gbogbo aiye simi, nwọn si gbe jẹ: nwọn bú jade ninu orin kikọ.
Nitõtọ, igi firi nyọ̀ ọ, ati igi kedari ti Lebanoni, wipe, Lati ìgba ti iwọ ti dubulẹ, kò si akegi ti o tọ̀ wa wá.
Ipò-okú lati isalẹ wá mì fun ọ lati pade rẹ li àbọ rẹ: o rú awọn okú dide fun ọ, ani gbogbo awọn alakoso aiye; o ti gbe gbogbo ọba awọn orilẹ-ède dide kuro lori itẹ wọn.
Gbogbo wọn o dahùn, nwọn o si wi fun ọ pe, Iwọ pẹlu ti di ailera gẹgẹ bi awa? iwọ ha dabi awa?
Ogo rẹ li ati sọ̀kalẹ si ipò-okú, ati ariwo durù rẹ: ekòlo ti tàn sabẹ rẹ, idin si bò ọ mọ ilẹ.
Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun wá, Iwọ Lusiferi, iràwọ owurọ! bawo li a ti ṣe ke ọ lu ilẹ, iwọ ti o ti ṣẹ́ awọn orilẹ-ède li apa!
Nitori iwọ ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja iràwọ Ọlọrun: emi o si joko lori oke ijọ enia ni iha ariwa:
Emi o goke kọja giga awọsanma: emi o dabi ọga-ogo jùlọ.
Ṣugbọn a o mu ọ sọkalẹ si ipò okú, si iha ihò.
Awọn ti o ri ọ yio tẹjumọ ọ, nwọn o si ronu rẹ pe, Eyi li ọkunrin na ti o mu aiye wárìrì, ti o mu ilẹ ọba mìtiti;
Ti o sọ aiye dàbi agìnju, ti o si pa ilu rẹ̀ run; ti kò dá awọn ondè rẹ̀ silẹ lati lọ ile?
Gbogbo ọba awọn orilẹ-ède, ani gbogbo wọn, dubulẹ ninu ogo, olukuluku ninu ile rẹ̀.
Ṣugbọn iwọ li a gbe sọnù kuro nibi iboji rẹ bi ẹka irira, bi aṣọ awọn ti a pa, awọn ti a fi idà gun li agunyọ, ti nsọkalẹ lọ si ihò okuta; bi okú ti a tẹ̀ mọlẹ.
A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai.
Mura ibi pipa fun awọn ọmọ rẹ̀, nitori aiṣedẽde awọn baba wọn; ki nwọn ki o má ba dide, ki nwọn ni ilẹ na, ki nwọn má si fi ilu-nla kun oju aiye.
Nitori emi o dide si wọn, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ke orukọ ati iyokù kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ, ni Oluwa wi.
Emi o si ṣe e ni ilẹ-ini fun õrẹ̀, ati àbata omi; emi o si fi ọwọ̀ iparun gbá a, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.