Isa 14:1-23
Isa 14:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI Oluwa yio ṣãnu fun Jakobu, yio si tun yan Israeli, yio si mu wọn gbe ilẹ wọn; alejò yio si dapọ̀ mọ wọn, nwọn o si faramọ ile Jakobu. Awọn enia yio si mu wọn, nwọn o si mu wọn wá si ipò wọn: ile Israeli yio si ni wọn ni ilẹ Oluwa, fun iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin: awọn ti o ti kó wọn ni igbekun ni nwọn o kó ni igbekun; nwọn o si ṣe akoso aninilara wọn. Yio si ṣe li ọjọ ti Oluwa yio fun ọ ni isimi kuro ninu ibanujẹ rẹ, ati kuro ninu ijaiya rẹ, ati kuro ninu oko-ẹru lile nibiti a ti mu ọ sìn, Ni iwọ o si fi ọba Babiloni ṣẹ̀fẹ yi, ti iwọ o si wipe, Aninilara nì ha ti ṣe dakẹ! alọnilọwọgbà wura dakẹ! Oluwa ti ṣẹ ọpá oluṣe-buburu, ati ọpá-alade awọn alakoso. Ẹniti o fi ibinu lù awọn enia lai dawọ duro, ẹniti o fi ibinu ṣe akoso awọn orilẹ-ède, li a nṣe inunibini si, lai dẹkun. Gbogbo aiye simi, nwọn si gbe jẹ: nwọn bú jade ninu orin kikọ. Nitõtọ, igi firi nyọ̀ ọ, ati igi kedari ti Lebanoni, wipe, Lati ìgba ti iwọ ti dubulẹ, kò si akegi ti o tọ̀ wa wá. Ipò-okú lati isalẹ wá mì fun ọ lati pade rẹ li àbọ rẹ: o rú awọn okú dide fun ọ, ani gbogbo awọn alakoso aiye; o ti gbe gbogbo ọba awọn orilẹ-ède dide kuro lori itẹ wọn. Gbogbo wọn o dahùn, nwọn o si wi fun ọ pe, Iwọ pẹlu ti di ailera gẹgẹ bi awa? iwọ ha dabi awa? Ogo rẹ li ati sọ̀kalẹ si ipò-okú, ati ariwo durù rẹ: ekòlo ti tàn sabẹ rẹ, idin si bò ọ mọ ilẹ. Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun wá, Iwọ Lusiferi, iràwọ owurọ! bawo li a ti ṣe ke ọ lu ilẹ, iwọ ti o ti ṣẹ́ awọn orilẹ-ède li apa! Nitori iwọ ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja iràwọ Ọlọrun: emi o si joko lori oke ijọ enia ni iha ariwa: Emi o goke kọja giga awọsanma: emi o dabi ọga-ogo jùlọ. Ṣugbọn a o mu ọ sọkalẹ si ipò okú, si iha ihò. Awọn ti o ri ọ yio tẹjumọ ọ, nwọn o si ronu rẹ pe, Eyi li ọkunrin na ti o mu aiye wárìrì, ti o mu ilẹ ọba mìtiti; Ti o sọ aiye dàbi agìnju, ti o si pa ilu rẹ̀ run; ti kò dá awọn ondè rẹ̀ silẹ lati lọ ile? Gbogbo ọba awọn orilẹ-ède, ani gbogbo wọn, dubulẹ ninu ogo, olukuluku ninu ile rẹ̀. Ṣugbọn iwọ li a gbe sọnù kuro nibi iboji rẹ bi ẹka irira, bi aṣọ awọn ti a pa, awọn ti a fi idà gun li agunyọ, ti nsọkalẹ lọ si ihò okuta; bi okú ti a tẹ̀ mọlẹ. A kì o sin ọ pọ̀ pẹlu wọn, nitoriti iwọ ti pa ilẹ rẹ run, o si ti pa awọn enia rẹ: iru awọn oluṣe buburu li a kì o darukọ lailai. Mura ibi pipa fun awọn ọmọ rẹ̀, nitori aiṣedẽde awọn baba wọn; ki nwọn ki o má ba dide, ki nwọn ni ilẹ na, ki nwọn má si fi ilu-nla kun oju aiye. Nitori emi o dide si wọn, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ke orukọ ati iyokù kuro ni Babiloni, ati ọmọ, ati ọmọ de ọmọ, ni Oluwa wi. Emi o si ṣe e ni ilẹ-ini fun õrẹ̀, ati àbata omi; emi o si fi ọwọ̀ iparun gbá a, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Isa 14:1-23 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA yóo ṣíjú àánú wo Jakọbu yóo tún yan Israẹli, yóo sì fi wọ́n sórí ilẹ̀ wọn. Àwọn àlejò yóo darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóo sì di ọ̀kan náà pẹlu ilé Jakọbu. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pada sí ilẹ̀ wọn, àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì di ẹrú fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọn yóo pada sọ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú di ẹrú, wọn yóo sì jọba lórí àwọn tí ó ni wọ́n lára. Nígbà tí OLUWA bá fun yín ní ìsinmi kúrò ninu làálàá ati rògbòdìyàn ati iṣẹ́ àṣekára tí wọn ń fi tipá mu yín ṣe, ẹ óo kọrin òwe bú ọba Babiloni pé: “Agbára aninilára ti pin ìpayà ojoojumọ ti dópin. OLUWA ti ṣẹ́ ọ̀pá àṣẹ àwọn ẹni ibi, ati ọ̀pá àṣẹ àwọn olórí tí wọn ń fi ibinu lu àwọn eniyan láì dáwọ́ dúró, tí wọn ń fi ibinu ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ń ṣe inúnibíni lemọ́lemọ́. Gbogbo ayé wà ní ìsinmi ati alaafia wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ayọ̀. Àwọn igi Sipirẹsi ń yọ̀ yín; àwọn igi Kedari ti Lẹbanoni sì ń sọ pé, ‘Láti ìgbà tí a ti rẹ ọba Babiloni sílẹ̀, kò sí agégi kan tí ó wá dààmú wa mọ́.’ “Isà òkú ti lanu sílẹ̀ láti pàdé rẹ bí o bá ti ń dé. Ó ta àwọn òkú ọ̀run jí láti kí ọ, àwọn tí wọ́n ṣe pataki ní àkókò wọn, Ó gbé gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn. Gbogbo wọn yóo wí fún ọ pé, ‘Àárẹ̀ ti mu yín gẹ́gẹ́ bí ó ti mú àwa náà. Ẹ ti dàbí i wa. A ti fa ògo yín ati ohùn hapu yín sinu isà òkú. Ìdin di ibùsùn tí ẹ sùn lé lórí àwọn kòkòrò ni ẹ sì fi bora bí aṣọ.’ “Ọba Babiloni, wò ó! Bí o ti jábọ́ láti ojú ọ̀run, ìwọ tí o dàbí ìràwọ̀ òwúrọ̀! Wò ó bí a ti sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀, ìwọ tí o ti pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè run rí. Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘N óo gòkè dé ọ̀run, n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run; n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan, ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré. N óo gòkè kọjá ìkùukùu ojú ọ̀run, n óo wá dàbí Olodumare.’ Ṣugbọn a já ọ lulẹ̀ sinu isà òkú, sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ọ yóo tẹjú mọ́ ọ, wọ́n óo fi ọ́ ṣe àríkọ́gbọ́n pé, ‘Ṣé ọkunrin tí ó ń kó ìpayà bá gbogbo ayé nìyí, tí ó ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì; ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀, tí ó sì pa àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ run, ẹni tí kì í dá àwọn tí ó bá wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀?’ Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dùbúlẹ̀ ninu ògo wọn olukuluku ninu ibojì tirẹ̀. Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ, bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé, tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù; tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun; àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta, bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa. A kò ní sin ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba yòókù, nítorí pé o ti pa ilẹ̀ rẹ run, o sì ti pa àwọn eniyan rẹ. Kí á má dárúkọ àwọn ìran ẹni ibi mọ́ títí lae! Ẹ múra láti pa àwọn ọmọ rẹ̀ run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, kí wọn má baà tún gbógun dìde, kí wọn gba gbogbo ayé kan, kí wọn sì kọ́ ọpọlọpọ ìlú sórí ilẹ̀ ayé.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo gbógun tì wọ́n, n óo pa orúkọ Babiloni rẹ́ ati ìyókù àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ̀, ati arọmọdọmọ wọn. N óo sọ ọ́ di ibùgbé òòrẹ̀, adágún omi yóo wà káàkiri inú rẹ, n óo sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Isa 14:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA yóò fi àánú hàn fún Jakọbu, yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn. Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn, wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn. Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin ní ilẹ̀ OLúWA. Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn. Ní ọjọ́ tí OLúWA yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé: Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí! OLúWA ti dá ọ̀pá ìkà náà, ọ̀pá àwọn aláṣẹ, èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀ pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró, nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin. Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà, wọ́n bú sí orin. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn igi kedari ti Lebanoni ń yọ̀ lórí rẹ wí pé, “Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí, kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.” Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Gbogbo wọn yóò dáhùn, wọn yóò wí fún ọ wí pé, “Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ìwọ náà ti dàbí wa.” Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì, pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ, àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá, ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà! A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí! Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀; Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.” Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ, wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ: “Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù, tí ó sì pa ìlú ńláńlá rẹ̀ run tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?” Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀. Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀, àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀, àwọn tí idà ti gún, àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun. Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀, A kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn, nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́ o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ. Ìran àwọn ìkà ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́. Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀ kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn. “Èmi yóò dìde sókè sí wọn,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà, àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,” ni OLúWA wí. Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí àti sí irà; Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a, ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.