Nitori ọ̀rọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idàkídà oloju meji lọ, o si ngúnni ani tìti de pipín ọkàn ati ẹmí niya, ati oríke ati ọrá inu egungun, on si ni olumọ̀ erò inu ati ète ọkàn. Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo. Njẹ bi a ti ni Olori Alufa nla kan, ti o ti la awọn ọ̀run kọja lọ, Jesu Ọmọ Ọlọrun, ẹ jẹ ki a di ijẹwọ wa mu ṣinṣin. Nitori a kò ni olori alufa ti kò le ṣai ba ni kẹdun ninu ailera wa, ẹniti a ti danwo li ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn lailẹ̀ṣẹ. Nitorina ẹ jẹ ki a wá si ibi itẹ ore-ọfẹ pẹlu igboiya, ki a le ri ãnu gbà, ki a si ri ore-ọfẹ lati mã rànnilọwọ ni akoko ti o wọ̀.
Kà Heb 4
Feti si Heb 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 4:12-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò