Gẹn 49:8-12

Gẹn 49:8-12 YBCV

Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ. Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide? Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀. Yio ma so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ ara àjara, ati ọmọ kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ mọ́ ara ãyo àjara; o ti fọ̀ ẹ̀wu rẹ̀ ninu ọtí-waini, ati aṣọ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ eso àjara: Oju rẹ̀ yio pọ́n fun ọtí-waini, ehín rẹ̀ yio si funfun fun wàra.