Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́, apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ; àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ. Juda dàbí kinniun, tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán, a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀. Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ, kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ. Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba, títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín; gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Yóo máa so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà, yóo so àwọ́nsìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà dáradára, bẹ́ẹ̀ ni oje àjàrà ni yóo máa fi fọ ẹ̀wù rẹ̀. Ojú rẹ̀ yóo pọ́n fún àmutẹ́rùn ọtí waini, eyín rẹ̀ yóo sì funfun fún àmutẹ́rùn omi wàrà.
Kà JẸNẸSISI 49
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JẸNẸSISI 49:8-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò