Gẹn 48:10-21

Gẹn 48:10-21 YBCV

Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra. Israeli si wi fun Josefu pe, Emi kò dába ati ri oju rẹ mọ́: si kiyesi i, Ọlọrun si fi irú-ọmọ rẹ hàn mi pẹlu. Josefu si mú wọn kuro li ẽkun rẹ̀, o si tẹriba, o dà oju rẹ̀ bolẹ. Josefu si mú awọn mejeji, Efraimu li ọwọ́ ọtún rẹ̀ si ọwọ́ òsi Israeli, ati Manasse lọwọ òsi rẹ̀, si ọwọ́ ọtún Israeli, o si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀. Israeli si nà ọwọ́ ọtún rẹ̀, o si fi lé Efraimu ẹniti iṣe aburo li ori, ati ọwọ́ òsi rẹ̀ lé ori Manasse, o mọ̃mọ̀ mu ọwọ́ rẹ̀ lọ bẹ̃: nitori Manasse ni iṣe akọ́bi. O si sure fun Josefu, o si wipe, Ọlọrun, niwaju ẹniti Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi rìn, Ọlọrun na ti o bọ́ mi lati ọjọ́ aiye mi titi di oni, Angeli na ti o dá mi ni ìde kuro ninu ibi gbogbo, ki o gbè awọn ọmọde wọnyi; ki a si pè orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi; ki nwọn ki o si di ọ̀pọlọpọ lãrin aiye. Nigbati Josefu ri pe baba rẹ̀ fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ lé Efraimu lori, inu rẹ̀ kò dùn: o si mú baba rẹ̀ li ọwọ́, lati ṣí i kuro li ori Efraimu si ori Manasse. Josefu si wi fun baba rẹ̀ pe, Bẹ̃kọ, baba mi: nitori eyi li akọ́bi; fi ọwọ́ ọtún rẹ lé e li ori. Baba rẹ̀ si kọ̀, o si wipe, Emi mọ̀, ọmọ mi, emi mọ̀: on pẹlu yio di enia, yio si pọ̀ pẹlu: ṣugbọ́n nitõtọ aburo rẹ̀ yio jù u lọ, irú-ọmọ rẹ̀ yio si di ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède. O si sure fun wọn li ọjọ́ na pe, Iwọ ni Israeli o ma fi sure, wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe nyin bi Efraimu on Manasse: bẹ̃li o fi Efraimu ṣaju Manasse. Israeli si wi fun Josefu pe, Wò o, emi kú: ṣugbọn Ọlọrun yio wà pẹlu nyin, yio si tun mú nyin lọ si ilẹ awọn baba nyin.