Gẹn 48:10-21

Gẹn 48:10-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra. Israeli si wi fun Josefu pe, Emi kò dába ati ri oju rẹ mọ́: si kiyesi i, Ọlọrun si fi irú-ọmọ rẹ hàn mi pẹlu. Josefu si mú wọn kuro li ẽkun rẹ̀, o si tẹriba, o dà oju rẹ̀ bolẹ. Josefu si mú awọn mejeji, Efraimu li ọwọ́ ọtún rẹ̀ si ọwọ́ òsi Israeli, ati Manasse lọwọ òsi rẹ̀, si ọwọ́ ọtún Israeli, o si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀. Israeli si nà ọwọ́ ọtún rẹ̀, o si fi lé Efraimu ẹniti iṣe aburo li ori, ati ọwọ́ òsi rẹ̀ lé ori Manasse, o mọ̃mọ̀ mu ọwọ́ rẹ̀ lọ bẹ̃: nitori Manasse ni iṣe akọ́bi. O si sure fun Josefu, o si wipe, Ọlọrun, niwaju ẹniti Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi rìn, Ọlọrun na ti o bọ́ mi lati ọjọ́ aiye mi titi di oni, Angeli na ti o dá mi ni ìde kuro ninu ibi gbogbo, ki o gbè awọn ọmọde wọnyi; ki a si pè orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi; ki nwọn ki o si di ọ̀pọlọpọ lãrin aiye. Nigbati Josefu ri pe baba rẹ̀ fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ lé Efraimu lori, inu rẹ̀ kò dùn: o si mú baba rẹ̀ li ọwọ́, lati ṣí i kuro li ori Efraimu si ori Manasse. Josefu si wi fun baba rẹ̀ pe, Bẹ̃kọ, baba mi: nitori eyi li akọ́bi; fi ọwọ́ ọtún rẹ lé e li ori. Baba rẹ̀ si kọ̀, o si wipe, Emi mọ̀, ọmọ mi, emi mọ̀: on pẹlu yio di enia, yio si pọ̀ pẹlu: ṣugbọ́n nitõtọ aburo rẹ̀ yio jù u lọ, irú-ọmọ rẹ̀ yio si di ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède. O si sure fun wọn li ọjọ́ na pe, Iwọ ni Israeli o ma fi sure, wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe nyin bi Efraimu on Manasse: bẹ̃li o fi Efraimu ṣaju Manasse. Israeli si wi fun Josefu pe, Wò o, emi kú: ṣugbọn Ọlọrun yio wà pẹlu nyin, yio si tun mú nyin lọ si ilẹ awọn baba nyin.

Gẹn 48:10-21 Yoruba Bible (YCE)

Ogbó ti mú kí ojú Israẹli di bàìbàì ní àkókò yìí, kò sì ríran dáradára mọ́. Josẹfu bá kó wọn súnmọ́ baba rẹ̀, baba rẹ̀ dì mọ́ wọn, ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu. Ó wí fún Josẹfu pé, “N kò lérò pé mo tún lè fi ojú kàn ọ́ mọ́, ṣugbọn Ọlọrun mú kí ó ṣeéṣe fún mi láti rí àwọn ọmọ rẹ.” Josẹfu bá kó wọn kúrò lẹ́sẹ̀ baba rẹ̀, òun gan-an náà wá dojúbolẹ̀ níwájú baba rẹ̀. Ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú Efuraimu, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ òsì baba rẹ̀, ó fi ọwọ́ òsì mú Manase, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ ọ̀tún baba rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí Israẹli na ọwọ́ rẹ̀ láti súre fún wọn, ó dábùú ọwọ́ rẹ̀ lórí ara wọn, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efuraimu lórí, ó sì gbé ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bẹ́ẹ̀ ni Efuraimu ni àbúrò, Manase sì ni àkọ́bí. Ó bá súre fún Josẹfu, ó ní, “Kí Ọlọrun tí Abrahamu ati Isaaki, baba mi, ń sìn bukun àwọn ọmọ wọnyi, kí Ọlọrun náà tí ó ti ń tọ́ mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní yìí bukun wọn, kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn; kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé, kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí Josẹfu rí i pé ọwọ́ ọ̀tún ni baba òun gbé lé Efuraimu lórí, kò dùn mọ́ ọn. Ó bá di ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé e kúrò lórí Efuraimu kí ó sì gbé e lórí Manase. Ó wí fún baba rẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, baba, eléyìí ni àkọ́bí, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.” Ṣugbọn baba rẹ̀ kọ̀, ó ní, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀, òun náà yóo di eniyan, yóo sì di alágbára, ṣugbọn sibẹsibẹ àbúrò rẹ̀ yóo jù ú lọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yóo sì di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.” Ó bá súre fún wọn ní ọjọ́ náà, ó ní, “Orúkọ yín ni Israẹli yóo fi máa súre fún eniyan, wọn yóo máa súre pé, ‘Kí Ọlọrun kẹ́ ọ bí ó ti kẹ́ Efuraimu ati Manase.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi Efuraimu ṣáájú Manase. Nígbà náà ni Israẹli sọ fún Josẹfu pé, “Àkókò ikú mi súnmọ́ etílé, ṣugbọn Ọlọrun yóo wà pẹlu rẹ, yóo sì mú ọ pada sí ilẹ̀ baba rẹ.

Gẹn 48:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn. Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.” Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba. Josẹfu sì mú àwọn méjèèjì, Efraimu ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkára rẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Israẹli, ó sì fi Manase sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Israẹli. Israẹli sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Efraimu lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàsé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Manase ni àkọ́bí. Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé, “Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀, Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní, Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu, kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí. Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi Abrahamu àti Isaaki, kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé, “Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé: ‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ” Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase. Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín.