Gẹn 48
48
Jakọbu Súre fún Efuraimu ati Manase
1O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi ni ẹnikan wi fun Josefu pe, Kiyesi i, ara baba rẹ kò dá: o si mú awọn ọmọ rẹ̀ mejeji, Manasse ati Efraimu pẹlu rẹ̀.
2Ẹnikan si sọ fun Jakobu, o si wipe, Kiyesi i, Josefu ọmọ rẹ tọ̀ ọ wá: Israeli si gbiyanju, o si joko lori akete.
3Jakobu si wi fun Josefu pe, Ọlọrun Olodumare farahàn mi ni Lusi ni ilẹ Kenaani, o si sure fun mi,
4O si wi fun mi pe, Kiyesĩ, Emi o mu ọ bisi i, Emi o mu ọ rẹ̀, Emi o si sọ ọ di ọ̀pọlọpọ enia; Emi o si fi ilẹ yi fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iní titi aiye.
5Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi.
6Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ti iwọ bí lẹhin wọn ni yio ṣe tirẹ, a o si ma pè wọn li orukọ awọn arakunrin wọn ni ilẹ iní wọn.
7Ati emi, nigbati mo ti Paddani wá, Rakeli kú lọwọ mi ni ilẹ Kenaani li ọ̀na, nigbati o kù diẹ ti a ba fi dé Efrati: emi si sin i nibẹ̀ li ọ̀na Efrati (eyi na ni Betlehemu).
8Israeli si wò awọn ọmọ Josefu, o si bère pe, Tani wọnyi?
9Josefu wi fun baba rẹ̀ pe, Awọn ọmọ mi ni, ti Ọlọrun fifun mi nihinyi. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mú wọn wá sọdọ mi, emi o si sure fun wọn.
10Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra.
11Israeli si wi fun Josefu pe, Emi kò dába ati ri oju rẹ mọ́: si kiyesi i, Ọlọrun si fi irú-ọmọ rẹ hàn mi pẹlu.
12Josefu si mú wọn kuro li ẽkun rẹ̀, o si tẹriba, o dà oju rẹ̀ bolẹ.
13Josefu si mú awọn mejeji, Efraimu li ọwọ́ ọtún rẹ̀ si ọwọ́ òsi Israeli, ati Manasse lọwọ òsi rẹ̀, si ọwọ́ ọtún Israeli, o si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀.
14Israeli si nà ọwọ́ ọtún rẹ̀, o si fi lé Efraimu ẹniti iṣe aburo li ori, ati ọwọ́ òsi rẹ̀ lé ori Manasse, o mọ̃mọ̀ mu ọwọ́ rẹ̀ lọ bẹ̃: nitori Manasse ni iṣe akọ́bi.
15O si sure fun Josefu, o si wipe, Ọlọrun, niwaju ẹniti Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi rìn, Ọlọrun na ti o bọ́ mi lati ọjọ́ aiye mi titi di oni,
16Angeli na ti o dá mi ni ìde kuro ninu ibi gbogbo, ki o gbè awọn ọmọde wọnyi; ki a si pè orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi; ki nwọn ki o si di ọ̀pọlọpọ lãrin aiye.
17Nigbati Josefu ri pe baba rẹ̀ fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ lé Efraimu lori, inu rẹ̀ kò dùn: o si mú baba rẹ̀ li ọwọ́, lati ṣí i kuro li ori Efraimu si ori Manasse.
18Josefu si wi fun baba rẹ̀ pe, Bẹ̃kọ, baba mi: nitori eyi li akọ́bi; fi ọwọ́ ọtún rẹ lé e li ori.
19Baba rẹ̀ si kọ̀, o si wipe, Emi mọ̀, ọmọ mi, emi mọ̀: on pẹlu yio di enia, yio si pọ̀ pẹlu: ṣugbọ́n nitõtọ aburo rẹ̀ yio jù u lọ, irú-ọmọ rẹ̀ yio si di ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède.
20O si sure fun wọn li ọjọ́ na pe, Iwọ ni Israeli o ma fi sure, wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe nyin bi Efraimu on Manasse: bẹ̃li o fi Efraimu ṣaju Manasse.
21Israeli si wi fun Josefu pe, Wò o, emi kú: ṣugbọn Ọlọrun yio wà pẹlu nyin, yio si tun mú nyin lọ si ilẹ awọn baba nyin.
22Pẹlupẹlu, emi si fi ilẹ-biri kan fun ọ jù awọn arakunrin rẹ lọ, ti mo fi idà ti on ti ọrun mi gbà lọwọ awọn enia Amori.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Gẹn 48: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.