ISRAELI si mú ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n ti on ti ohun gbogbo ti o ní, o si dé Beer-ṣeba, o si rú ẹbọ si Ọlọrun Isaaki baba rẹ̀. Ọlọrun si bá Israeli sọ̀rọ li ojuran li oru, o si wipe, Jakobu, Jakobu. O si wipe, Emi niyi. O si wipe, Emi li Ọlọrun, Ọlọrun baba rẹ: má bẹ̀ru lati sọkalẹ lọ si ilẹ Egipti; nitori ibẹ̀ li emi o gbé sọ iwọ di orilẹ-ède nla. Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé. Jakobu si dide lati Beer-ṣeba lọ: awọn ọmọ Israeli si mú Jakobu baba wọn lọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wọn, ati awọn aya wọn, ninu kẹkẹ́-ẹrù ti Farao rán lati mú u lọ. Nwọn si mú ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ti nwọn ní ni ilẹ Kenaani, nwọn si wá si Egipti, Jakobu, ati gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: Awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin awọn ọmọ rẹ̀, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ li o mú pẹlu rẹ̀ wá si ilẹ Egipti.
Kà Gẹn 46
Feti si Gẹn 46
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 46:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò