Gẹn 46:1-7
Gẹn 46:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
ISRAELI si mú ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n ti on ti ohun gbogbo ti o ní, o si dé Beer-ṣeba, o si rú ẹbọ si Ọlọrun Isaaki baba rẹ̀. Ọlọrun si bá Israeli sọ̀rọ li ojuran li oru, o si wipe, Jakobu, Jakobu. O si wipe, Emi niyi. O si wipe, Emi li Ọlọrun, Ọlọrun baba rẹ: má bẹ̀ru lati sọkalẹ lọ si ilẹ Egipti; nitori ibẹ̀ li emi o gbé sọ iwọ di orilẹ-ède nla. Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé. Jakobu si dide lati Beer-ṣeba lọ: awọn ọmọ Israeli si mú Jakobu baba wọn lọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wọn, ati awọn aya wọn, ninu kẹkẹ́-ẹrù ti Farao rán lati mú u lọ. Nwọn si mú ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ti nwọn ní ni ilẹ Kenaani, nwọn si wá si Egipti, Jakobu, ati gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: Awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin awọn ọmọ rẹ̀, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ li o mú pẹlu rẹ̀ wá si ilẹ Egipti.

Gẹn 46:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Israẹli di gbogbo ohun tí ó ní, ó kó lọ sí Beeriṣeba, ó lọ rúbọ sí Ọlọrun Isaaki, baba rẹ̀. Ọlọrun bá a sọ̀rọ̀ lójú ìran lóru, ó pè é, ó ní, “Jakọbu, Jakọbu.” Ó dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” Ọlọrun wí pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, má fòyà rárá láti lọ sí Ijipti, nítorí pé n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. N óo bá ọ lọ sí Ijipti, n óo sì tún mú ọ pada wá, ọwọ́ Josẹfu ni o óo sì dákẹ́ sí.” Jakọbu bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Beeriṣeba. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé e sinu ọkọ̀ tí Farao fi ranṣẹ sí i pé kí wọ́n fi gbé e wá, wọ́n sì kó àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ pẹlu wọn. Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun tí wọ́n ní ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n lọ sí Ijipti. Gbogbo ilé rẹ̀ patapata ni Jakọbu kó lọ́wọ́ lọ sí Ijipti, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, gbogbo wọn ni ó kó lọ sí Ijipti patapata.
Gẹn 46:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀. Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnrarẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.” Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀: Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti. Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Ejibiti.