Nwọn si goke lati ilẹ Egipti lọ, nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani. Nwọn si wi fun u pe, Josefu mbẹ lãye sibẹ̀, on si ni bãlẹ gbogbo ilẹ Egipti. O si rẹ̀ Jakobu dé inu nitori ti kò gbà wọn gbọ́. Nwọn si sọ ọ̀rọ Josefu gbogbo fun u, ti o wi fun wọn: nigbati o si ri kẹkẹ́-ẹrù ti Josefu rán wá lati fi mú u lọ, ọkàn Jakobu baba wọn sọji: Israeli si wipe, O tó; Josefu ọmọ mi mbẹ lãye sibẹ̀; emi o lọ ki nsi ri i ki emi ki o to kú.
Kà Gẹn 45
Feti si Gẹn 45
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 45:25-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò