Gẹn 45:25-28
Gẹn 45:25-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si goke lati ilẹ Egipti lọ, nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani. Nwọn si wi fun u pe, Josefu mbẹ lãye sibẹ̀, on si ni bãlẹ gbogbo ilẹ Egipti. O si rẹ̀ Jakobu dé inu nitori ti kò gbà wọn gbọ́. Nwọn si sọ ọ̀rọ Josefu gbogbo fun u, ti o wi fun wọn: nigbati o si ri kẹkẹ́-ẹrù ti Josefu rán wá lati fi mú u lọ, ọkàn Jakobu baba wọn sọji: Israeli si wipe, O tó; Josefu ọmọ mi mbẹ lãye sibẹ̀; emi o lọ ki nsi ri i ki emi ki o to kú.
Gẹn 45:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Josẹfu ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Josẹfu fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jakọbu, baba wọn sọ. Israẹli sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Josẹfu ọmọ mi wà láààyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”

Gẹn 45:25-28 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n bá kúrò ní Ijipti, wọ́n pada sọ́dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sọ fún un pé, “Josẹfu kò kú, ó wà láàyè, ati pé òun ni alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, orí rẹ̀ fò lọ fee, kò kọ́ gbà wọ́n gbọ́. Ṣugbọn nígbà tí ó gbọ́ gbogbo ohun tí Josẹfu wí fún wọn, tí ó tún rí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin tí Josẹfu fi ranṣẹ pé kí wọ́n fi gbé òun wá, ara rẹ̀ wálẹ̀. Israẹli bá dáhùn, ó ní, “Josẹfu, ọmọ mi wà láàyè! Ó ti parí, n óo lọ fi ojú kàn án kí n tó kú.”