O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi, li agbọti ọba Egipti ati alasè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Egipti oluwa wọn.
Farao si binu si meji ninu awọn ijoye rẹ̀, si olori awọn agbọti, ati si olori awọn alasè.
O si fi wọn sinu túbu ninu ile olori ẹṣọ́, sinu túbu ti a gbé dè Josefu si.
Olori ẹṣọ́ na si fi Josefu jẹ́ olori wọn; o si nṣe itọju wọn: nwọn si pẹ diẹ ninu túbu na.
Awọn mejeji si lá alá kan, olukuluku lá alá tirẹ̀ li oru kanna, olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀, agbọti ati alasè ọba Egipti, ti a dè sinu túba na.
Josefu si wọle tọ̀ wọn lọ li owurọ̀, o si wò wọn, si kiyesi i, nwọn fajuro.
O si bi awọn ijoye Farao ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ile túbu oluwa rẹ̀ pe, Ẽṣe ti oju nyin fi buru bẹ̃ loni?
Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi.
Olori agbọti si rọ́ alá tirẹ̀ fun Josefu, o si wi fun u pe, Li oju alá mi, kiyesi i, àjara kan wà niwaju mi,
Ati lara àjara na li ẹka mẹta wà; o si rudi, itana rẹ̀ si tú jade; ati ṣiri rẹ̀ si so eso-ájara ti o pọ́n.
Ago Farao si wà li ọwọ́ mi: emi si mú eso-àjara na, mo si fún wọn sinu ago Farao, mo si fi ago na lé Farao lọwọ.
Josefu si wi fun u pe, Itumọ̀ rẹ̀ li eyi: ẹka mẹta nì, ijọ́ mẹta ni:
Ni ijọ́ mẹta oni, ni Farao yio gbe ori rẹ soke yio si mú ọ pada si ipò rẹ: iwọ o si fi ago lé Farao li ọwọ́ gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju nigbati iwọ ti iṣe agbọti rẹ̀.
Ṣugbọn ki o ranti mi nigbati o ba dara fun ọ, ki o si fi iṣeun rẹ hàn fun mi, emi bẹ̀ ọ, ki o si da orukọ mi fun Farao, ki o si mú mi jade ninu ile yi.
Nitõtọ jíji li a jí mi tà lati ilẹ awọn Heberu wá: ati nihinyi pẹlu, emi kò ṣe nkan ti nwọn fi fi mi sinu ihò-túbu yi.
Nigbati olori alasè ri pe itumọ̀ alá na dara, o si wi fun Josefu pe, Emi wà li oju-alá mi pẹlu, si kiyesi i, emi rù agbọ̀n àkara funfun mẹta li ori mi:
Ati ninu agbọ̀n ti o wà loke li onirũru onjẹ sisè wà fun Farao; awọn ẹiyẹ si njẹ ẹ ninu agbọ̀n na ti o wà li ori mi.
Josefu si dahún o si wipe, itumọ̀ rẹ̀ li eyi: agbọ̀n mẹta nì, ijọ́ mẹta ni.
Ni ijọ́ mẹta oni ni Farao yio gbé ori rẹ kuro lara rẹ, yio si so ọ rọ̀ lori igi kan; awọn ẹiyẹ yio si ma jẹ ẹran ara rẹ kuro lara rẹ.
O si ṣe ni ijọ́ kẹta, ti iṣe ọjọ́ ibí Farao, ti o sè àse fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ gbogbo: o si gbé ori olori agbọti soke ati ti olori awọn alasè lãrin awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.
O si tun mú olori agbọti pada si ipò rẹ̀; on si fi ago lé Farao li ọwọ́:
Ṣugbọn olori alasè li o sorọ̀: bi Josefu ti tumọ̀ alá na fun wọn.
Ṣugbọn olori agbọti kò ranti Josefu, o gbagbe rẹ̀.