Gẹn 40:1-23
Gẹn 40:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi, li agbọti ọba Egipti ati alasè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Egipti oluwa wọn. Farao si binu si meji ninu awọn ijoye rẹ̀, si olori awọn agbọti, ati si olori awọn alasè. O si fi wọn sinu túbu ninu ile olori ẹṣọ́, sinu túbu ti a gbé dè Josefu si. Olori ẹṣọ́ na si fi Josefu jẹ́ olori wọn; o si nṣe itọju wọn: nwọn si pẹ diẹ ninu túbu na. Awọn mejeji si lá alá kan, olukuluku lá alá tirẹ̀ li oru kanna, olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀, agbọti ati alasè ọba Egipti, ti a dè sinu túba na. Josefu si wọle tọ̀ wọn lọ li owurọ̀, o si wò wọn, si kiyesi i, nwọn fajuro. O si bi awọn ijoye Farao ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ile túbu oluwa rẹ̀ pe, Ẽṣe ti oju nyin fi buru bẹ̃ loni? Nwọn si wi fun u pe, Awa lá alá, kò si sí onitumọ̀ rẹ̀. Josefu si wi fun wọn pe, Ti Ọlọrun ki itumọ̀ iṣe ndan? emi bẹ̀ nyin, ẹ rọ́ wọn fun mi. Olori agbọti si rọ́ alá tirẹ̀ fun Josefu, o si wi fun u pe, Li oju alá mi, kiyesi i, àjara kan wà niwaju mi, Ati lara àjara na li ẹka mẹta wà; o si rudi, itana rẹ̀ si tú jade; ati ṣiri rẹ̀ si so eso-ájara ti o pọ́n. Ago Farao si wà li ọwọ́ mi: emi si mú eso-àjara na, mo si fún wọn sinu ago Farao, mo si fi ago na lé Farao lọwọ. Josefu si wi fun u pe, Itumọ̀ rẹ̀ li eyi: ẹka mẹta nì, ijọ́ mẹta ni: Ni ijọ́ mẹta oni, ni Farao yio gbe ori rẹ soke yio si mú ọ pada si ipò rẹ: iwọ o si fi ago lé Farao li ọwọ́ gẹgẹ bi ti ìgba iṣaju nigbati iwọ ti iṣe agbọti rẹ̀. Ṣugbọn ki o ranti mi nigbati o ba dara fun ọ, ki o si fi iṣeun rẹ hàn fun mi, emi bẹ̀ ọ, ki o si da orukọ mi fun Farao, ki o si mú mi jade ninu ile yi. Nitõtọ jíji li a jí mi tà lati ilẹ awọn Heberu wá: ati nihinyi pẹlu, emi kò ṣe nkan ti nwọn fi fi mi sinu ihò-túbu yi. Nigbati olori alasè ri pe itumọ̀ alá na dara, o si wi fun Josefu pe, Emi wà li oju-alá mi pẹlu, si kiyesi i, emi rù agbọ̀n àkara funfun mẹta li ori mi: Ati ninu agbọ̀n ti o wà loke li onirũru onjẹ sisè wà fun Farao; awọn ẹiyẹ si njẹ ẹ ninu agbọ̀n na ti o wà li ori mi. Josefu si dahún o si wipe, itumọ̀ rẹ̀ li eyi: agbọ̀n mẹta nì, ijọ́ mẹta ni. Ni ijọ́ mẹta oni ni Farao yio gbé ori rẹ kuro lara rẹ, yio si so ọ rọ̀ lori igi kan; awọn ẹiyẹ yio si ma jẹ ẹran ara rẹ kuro lara rẹ. O si ṣe ni ijọ́ kẹta, ti iṣe ọjọ́ ibí Farao, ti o sè àse fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ gbogbo: o si gbé ori olori agbọti soke ati ti olori awọn alasè lãrin awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. O si tun mú olori agbọti pada si ipò rẹ̀; on si fi ago lé Farao li ọwọ́: Ṣugbọn olori alasè li o sorọ̀: bi Josefu ti tumọ̀ alá na fun wọn. Ṣugbọn olori agbọti kò ranti Josefu, o gbagbe rẹ̀.

Gẹn 40:1-23 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò kan, agbọ́tí Farao, ọba Ijipti, ati olórí alásè rẹ̀ ṣẹ ọba. Inú bí Farao sí àwọn iranṣẹ rẹ̀ mejeeji yìí, ó sì jù wọ́n sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Josẹfu wà. Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fi wọ́n sábẹ́ àkóso Josẹfu, wọ́n sì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún ìgbà díẹ̀. Ní òru ọjọ́ kan, agbọ́tí ọba ati olórí alásè náà lá àlá kan, àlá tí olukuluku lá sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́ tí Josẹfu rí wọn, ó rí i pé ọkàn wọn dàrú. Ó bá bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ojú yín fi rẹ̀wẹ̀sì lónìí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lá àlá kan ni, a kò sì rí ẹni bá wa túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣebí Ọlọrun ni ó ni ìtumọ̀ àlá? Ẹ rọ́ àlá náà fún mi.” Agbọ́tí bá rọ́ àlá tirẹ̀ fún Josẹfu, ó ní, “Mo rí ìtàkùn àjàrà kan lójú àlá. Ìtàkùn náà ní ẹ̀ka mẹta, bí ewé rẹ̀ ti yọ, lẹsẹkẹsẹ, ni ó tanná, ó so, èso rẹ̀ sì pọ́n. Ife Farao wà ní ọwọ́ mi, mo bá mú èso àjàrà náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí fún un sinu ife Farao, mo sì gbé ife náà lé Farao lọ́wọ́.” Josẹfu bá sọ fún un pé, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn ẹ̀ka mẹta tí o rí dúró fún ọjọ́ mẹta. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta Farao yóo yọ ọ́ jáde, yóo dáríjì ọ́, yóo sì fi ọ́ sí ipò rẹ pada, o óo sì tún máa gbé ọtí fún Farao bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ṣugbọn ṣá o, ranti mi nígbà tí ó bá dára fún ọ, jọ̀wọ́, ṣe mí lóore kan, ròyìn mi fún Farao, kí Farao sì yọ mí kúrò ninu àhámọ́ yìí. Nítorí pé jíjí ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ Heberu, ati pé níhìn-ín gan-an, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ tí wọ́n fi gbé mi jù sẹ́wọ̀n yìí.” Alásè rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi náà lá àlá kan, mo ru agbọ̀n àkàrà mẹta lórí, lójú àlá. Mo rí i pé oríṣìíríṣìí oúnjẹ Farao ni ó wà ninu agbọ̀n tí ó wà ní òkè patapata, mo bá tún rí i tí àwọn ẹyẹ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn oúnjẹ yìí ní orí mi.” Josẹfu dáhùn, ó ní, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn agbọ̀n mẹta náà dúró fún ọjọ́ mẹta. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, Farao ọba yóo yọ ọ́ jáde níhìn-ín, yóo bẹ́ ọ lórí, yóo gbé ọ kọ́ igi, àwọn ẹyẹ yóo sì jẹ ẹran ara rẹ.” Ní ọjọ́ kẹta tíí ṣe ọjọ́ ìbí Farao, ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì mú agbọ́tí rẹ̀ ati alásè rẹ̀ jáde sí ààrin àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó dá agbọ́tí pada sí ipò rẹ̀ láti máa gbé ọtí fún un, ṣugbọn ó pàṣẹ kí wọ́n lọ so olórí alásè kọ́ igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti túmọ̀ àlá wọn fún wọn. Ṣugbọn olórí agbọ́tí kò ranti Josẹfu mọ, ó gbàgbé rẹ̀ patapata.
Gẹn 40:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Ejibiti, olúwa wọn. Farao sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè, Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà. Olórí ẹ̀ṣọ́ sì yan Josẹfu láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀. Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà—olórí agbọ́tí àti olórí alásè ọba Ejibiti, tí a dè sínú túbú, lá àlá ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn. Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?” Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.” Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi, Mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n. Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.” Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá. Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Farao, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín. Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.” Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá: Mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí, Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.” Josẹfu dáhùn, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta. Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.” Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n. Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́, Ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti sọ fún wọn nínú ìtumọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn. Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Josẹfu mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀.