JAKOBU si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n, o si wá si ilẹ awọn ara ìla-õrùn.
O si wò, si kiyesi i, kanga kan ninu oko, si kiyesi i, agbo-agutan mẹta dubulẹ tì i; nitori pe, lati inu kanga na wá ni nwọn ti nfi omi fun awọn agbo-agutan: okuta nla si wà li ẹnu kanga na.
Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀.
Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá.
O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ.
O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran.
O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn.
Nwọn si wipe, Awa kò le ṣe e, titi gbogbo awọn agbo-ẹran yio fi wọjọ pọ̀, ti nwọn o si fi yí okuta kuro li ẹnu kanga; nigbana li a le fun awọn agutan li omi.
Nigbati o si mba wọn sọ̀rọ lọwọ, Rakeli de pẹlu awọn agutan baba rẹ̀: on li o sa nṣọ́ wọn.
O si ṣe, nigbati Jakobu ri Rakeli, ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ̀, ati agutan Labani, arakunrin iya rẹ̀, ni Jakobu si sunmọ ibẹ̀, o si yí okuta kuro li ẹnu kanga, o si fi omi fun gbogbo agbo-ẹran Labani, arakunrin iya rẹ̀.
Jakobu si fi ẹnu kò Rakeli li ẹnu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.
Jakobu si wi fun Rakeli pe arakunrin baba rẹ̀ li on, ati pe, ọmọ Rebeka li on: ọmọbinrin na si sure o si sọ fun baba rẹ̀.
O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani.
Labani si wi fun u pe, egungun on ẹran-ara mi ni iwọ iṣe nitõtọ. O si bá a joko ni ìwọn oṣù kan.
Labani si wi fun Jakobu pe, Iwọ o ha ma sìn mi li asan bi, nitoriti iwọ iṣe arakunrin mi? elo li owo iṣẹ rẹ, wi fun mi?
Labani si ni ọmọbinrin meji: orukọ ẹgbọ́n a ma jẹ Lea, orukọ aburo a si ma jẹ Rakeli.
Oju Lea kò li ẹwà, ṣugbọn Rakeli ṣe arẹwà, o si wù ni.
Jakobu si fẹ́ Rakeli; o si wipe, Emi o sìn ọ li ọdún meje nitori Rakeli, ọmọbinrin rẹ abikẹhin.
Labani si wipe, O san lati fi i fun ọ, jù ki nfi i fun ẹlomiran lọ: ba mi joko.
Jakobu si sìn i li ọdún meje fun Rakeli; nwọn sì dabi ijọ́ melokan li oju rẹ̀ nitori ifẹ́ ti o fẹ́ ẹ.
Jakobu si wi fun Labani pe, Fi aya mi fun mi, nitoriti ọjọ́ mi pé, ki emi ki o le wọle tọ̀ ọ.
Labani si pè gbogbo awọn enia ibẹ̀ jọ, o si se àse.
O si ṣe li alẹ, o mú Lea ọmọbinrin rẹ̀, o sìn i tọ̀ ọ wá; on si wọle tọ̀ ọ lọ.
Labani si fi Silpa, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fun Lea, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀.
O si ṣe, li owurọ, wò o, o jẹ́ Lea: o si wi fun Labani pe, Ẽwo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? nitori Rakeli ki mo ṣe sìn ọ, njẹ ẽhatiṣe ti o fi ṣe erú si mi?
Labani si wi fun u pe, A kò gbọdọ ṣe bẹ̃ ni ilẹ wa, lati sìn aburo ṣaju ẹgbọ́n.
Ṣe ọ̀sẹ ti eleyi pé, awa o si fi eyi fun ọ pẹlu, nitori ìsin ti iwọ o sìn mi li ọdún meje miran si i.
Jakobu si ṣe bẹ̃, o si ṣe ọ̀sẹ rẹ̀ pé: o si fi Rakeli ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya pẹlu.
Labani si fi Bilha, ọmọbinrin ọdọ rẹ̀, fun Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀.
O si wọle tọ̀ Rakeli pẹlu, o si fẹ́ Rakeli jù Lea lọ, o si sìn i li ọdún meje miran si i.
Nigbati OLUWA si ri i pe a korira Lea, o ṣi i ni inu: ṣugbọn Rakeli yàgan.
Lea si loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Reubeni: nitori ti o wipe, OLUWA wò ìya mi nitõtọ: njẹ nitorina, ọkọ mi yio fẹ́ mi.
O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Nitori ti OLUWA ti gbọ́ pe a korira mi, nitorina li o ṣe fun mi li ọmọ yi pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Simeoni.
O si tun loyun, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Njẹ nigbayi li ọkọ mi yio faramọ́ mi, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹta fun u: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Lefi.
O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan: o si wipe, Nigbayi li emi o yìn OLUWA: nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Judah; o si dẹkun bíbi.