Gẹn 29:1-35
Gẹn 29:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn. Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà. Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.” Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ ọmọ Nahori?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.” Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.” Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.” Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi. Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un. Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.” Lẹ́yìn tí Jakọbu sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan, Labani wí fún Jakọbu pé, “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!” Wàyí o, Labani ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rakeli. Lea kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rakeli ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. Jakọbu sì fẹ́ràn Rakeli, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rakeli ọmọ rẹ ní aya.” Labani sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí náà wà ní ọ̀dọ̀ mi.” Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀. Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.” Labani sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àsè ìyàwó fún wọ́n. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Labani mú Lea tọ Jakọbu lọ. Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Labani sì fi Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Lea gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́. Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?” Labani sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí náà, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.” Jakọbu sì gbà láti sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Labani sì fi Rakeli ọmọ rẹ̀ fún un bí aya. Labani sì fi Biliha ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rakeli bí ìránṣẹ́. Jakọbu sì bá Rakeli náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rakeli ju Lea lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó ṣí i ni inú ṣùgbọ́n Rakeli yàgàn. Lea sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Reubeni, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Simeoni, wí pé “Nítorí tí OLúWA ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni ọkọ mi yóò fi ara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Lefi. Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin OLúWA.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Juda. Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró.
Gẹn 29:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
JAKOBU si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n, o si wá si ilẹ awọn ara ìla-õrùn. O si wò, si kiyesi i, kanga kan ninu oko, si kiyesi i, agbo-agutan mẹta dubulẹ tì i; nitori pe, lati inu kanga na wá ni nwọn ti nfi omi fun awọn agbo-agutan: okuta nla si wà li ẹnu kanga na. Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀. Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá. O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ. O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran. O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn. Nwọn si wipe, Awa kò le ṣe e, titi gbogbo awọn agbo-ẹran yio fi wọjọ pọ̀, ti nwọn o si fi yí okuta kuro li ẹnu kanga; nigbana li a le fun awọn agutan li omi. Nigbati o si mba wọn sọ̀rọ lọwọ, Rakeli de pẹlu awọn agutan baba rẹ̀: on li o sa nṣọ́ wọn. O si ṣe, nigbati Jakobu ri Rakeli, ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ̀, ati agutan Labani, arakunrin iya rẹ̀, ni Jakobu si sunmọ ibẹ̀, o si yí okuta kuro li ẹnu kanga, o si fi omi fun gbogbo agbo-ẹran Labani, arakunrin iya rẹ̀. Jakobu si fi ẹnu kò Rakeli li ẹnu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. Jakobu si wi fun Rakeli pe arakunrin baba rẹ̀ li on, ati pe, ọmọ Rebeka li on: ọmọbinrin na si sure o si sọ fun baba rẹ̀. O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani. Labani si wi fun u pe, egungun on ẹran-ara mi ni iwọ iṣe nitõtọ. O si bá a joko ni ìwọn oṣù kan. Labani si wi fun Jakobu pe, Iwọ o ha ma sìn mi li asan bi, nitoriti iwọ iṣe arakunrin mi? elo li owo iṣẹ rẹ, wi fun mi? Labani si ni ọmọbinrin meji: orukọ ẹgbọ́n a ma jẹ Lea, orukọ aburo a si ma jẹ Rakeli. Oju Lea kò li ẹwà, ṣugbọn Rakeli ṣe arẹwà, o si wù ni. Jakobu si fẹ́ Rakeli; o si wipe, Emi o sìn ọ li ọdún meje nitori Rakeli, ọmọbinrin rẹ abikẹhin. Labani si wipe, O san lati fi i fun ọ, jù ki nfi i fun ẹlomiran lọ: ba mi joko. Jakobu si sìn i li ọdún meje fun Rakeli; nwọn sì dabi ijọ́ melokan li oju rẹ̀ nitori ifẹ́ ti o fẹ́ ẹ. Jakobu si wi fun Labani pe, Fi aya mi fun mi, nitoriti ọjọ́ mi pé, ki emi ki o le wọle tọ̀ ọ. Labani si pè gbogbo awọn enia ibẹ̀ jọ, o si se àse. O si ṣe li alẹ, o mú Lea ọmọbinrin rẹ̀, o sìn i tọ̀ ọ wá; on si wọle tọ̀ ọ lọ. Labani si fi Silpa, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fun Lea, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. O si ṣe, li owurọ, wò o, o jẹ́ Lea: o si wi fun Labani pe, Ẽwo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? nitori Rakeli ki mo ṣe sìn ọ, njẹ ẽhatiṣe ti o fi ṣe erú si mi? Labani si wi fun u pe, A kò gbọdọ ṣe bẹ̃ ni ilẹ wa, lati sìn aburo ṣaju ẹgbọ́n. Ṣe ọ̀sẹ ti eleyi pé, awa o si fi eyi fun ọ pẹlu, nitori ìsin ti iwọ o sìn mi li ọdún meje miran si i. Jakobu si ṣe bẹ̃, o si ṣe ọ̀sẹ rẹ̀ pé: o si fi Rakeli ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya pẹlu. Labani si fi Bilha, ọmọbinrin ọdọ rẹ̀, fun Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀. O si wọle tọ̀ Rakeli pẹlu, o si fẹ́ Rakeli jù Lea lọ, o si sìn i li ọdún meje miran si i. Nigbati OLUWA si ri i pe a korira Lea, o ṣi i ni inu: ṣugbọn Rakeli yàgan. Lea si loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Reubeni: nitori ti o wipe, OLUWA wò ìya mi nitõtọ: njẹ nitorina, ọkọ mi yio fẹ́ mi. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Nitori ti OLUWA ti gbọ́ pe a korira mi, nitorina li o ṣe fun mi li ọmọ yi pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Simeoni. O si tun loyun, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Njẹ nigbayi li ọkọ mi yio faramọ́ mi, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹta fun u: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Lefi. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan: o si wipe, Nigbayi li emi o yìn OLUWA: nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Judah; o si dẹkun bíbi.
Gẹn 29:1-35 Yoruba Bible (YCE)
Jakọbu tún ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, nígbà tí ó ṣe, ó dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn. Bí ó ti gbójú sókè, ó rí kànga kan ninu pápá, ati agbo aguntan mẹta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí pé láti inú kànga yìí ni wọ́n ti ń fún àwọn aguntan náà ní omi mu. Òkúta tí wọ́n sì yí dí ẹnu kànga náà tóbi pupọ. Nígbà tí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá da aguntan wọn dé ìdí kànga yìí ni wọ́n tó ń yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga. Lẹ́yìn náà, wọn á fún àwọn aguntan wọ́n lómi mu, wọ́n á sì yí òkúta náà pada sẹ́nu kànga. Jakọbu bá bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Harani ni.” Ó tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ Nahori?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A mọ̀ ọ́n.” Ó tún bi wọ́n pé, “Ṣé alaafia ni ó wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, wò ó, Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, ni ó ń da aguntan bọ̀ ní ọ̀kánkán yìí.” Jakọbu sọ pé, “Oòrùn ṣì wà lókè, kò tíì tó àkókò láti kó àwọn ẹran jọ sójú kan, ẹ tètè fún àwọn aguntan ní omi mu, kí ẹ sì dà wọ́n pada lọ jẹ koríko sí i.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò ṣeéṣe, àfi bí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá dé tán, tí a bá yí òkúta kúrò lórí kànga, nígbà náà ni a tó lè fún àwọn aguntan ní omi mu.” Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakẹli dé pẹlu agbo aguntan baba rẹ̀, nítorí pé òun ni ó ń tọ́jú wọn. Nígbà tí Jakọbu rí Rakẹli, ọmọ Labani, tíí ṣe arakunrin ìyá rẹ̀, ati agbo aguntan Labani, ó yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga, ó sì pọn omi fún wọn. Jakọbu bá fi ẹnu ko Rakẹli lẹ́nu, ó sì bú sẹ́kún. Ó sọ fún Rakẹli pé, ìbátan baba rẹ̀ ni òun jẹ́, ati pé ọmọ Rebeka ni òun. Rakẹli bá sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. Nígbà tí Labani gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà pé, Jakọbu ọmọ arabinrin òun dé, ó sáré lọ pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sí ilé. Jakọbu ròyìn ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún Labani. Labani bá dá a lọ́kàn le, ó ní, “Láìsí àní àní, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá” Jakọbu sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún oṣù kan. Lẹ́yìn náà Labani sọ fún un pé, “O wá gbọdọ̀ máa sìn mí lásán nítorí pé o jẹ́ ìbátan mi? Sọ fún mi, èló ni o fẹ́ máa gbà?” Labani ní ọmọbinrin meji, èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, èyí àbúrò sì ń jẹ́ Rakẹli. Ojú Lea kò fi bẹ́ẹ̀ fanimọ́ra, ṣugbọn Rakẹli jẹ́ arẹwà, ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. Jakọbu nífẹ̀ẹ́ Rakẹli, nítorí náà, ó sọ fún Labani pé, “N óo sìn ọ́ ní ọdún meje nítorí Rakẹli, ọmọ rẹ kékeré.” Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó tẹ́ mi lọ́rùn láti fún ọ ju kí n fún ẹni ẹlẹ́ni lọ. Máa bá mi ṣiṣẹ́.” Jakọbu bá sin Labani fún ọdún meje nítorí Rakẹli, ó sì dàbí ọjọ́ mélòó kan lójú rẹ̀ nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí Rakẹli. Nígbà tí ó yá, Jakọbu sọ fún Labani pé, “Fún mi ní aya mi, kí á lè ṣe igbeyawo, nítorí ọjọ́ ti pé.” Labani bá pe gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀ jọ, ó se àsè ńlá fún wọn. Ṣugbọn nígbà tí ó di àṣáálẹ́, Lea ni wọ́n mú wá fún Jakọbu dípò Rakẹli, Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Labani fi Silipa ẹrubinrin rẹ̀ fún Lea pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, Jakọbu rí i pé Lea ni wọ́n mú wá fún òun. Ó bi Labani, ó ní, “Irú kí ni o ṣe sí mi yìí? Ṣebí nítorí Rakẹli ni mo fi sìn ọ́? Èéṣe tí o tàn mí jẹ?” Labani dáhùn, ó ní, “Ní ilẹ̀ tiwa níhìn-ín, àwa kì í fi àbúrò fọ́kọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n. Fara balẹ̀ parí àwọn ètò ọ̀sẹ̀ igbeyawo ti eléyìí, n óo sì fún ọ ní ekeji náà, ṣugbọn o óo tún sìn mí ní ọdún meje sí i.” Jakọbu gbà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ọ̀sẹ̀ igbeyawo Lea parí, lẹ́yìn náà Labani fa Rakẹli, ọmọ rẹ̀ fún un. Labani fi Biliha, ẹrubinrin rẹ̀ fún Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún un. Jakọbu bá Rakẹli náà lòpọ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ju Lea lọ, ó sì sin Labani fún ọdún meje sí i. Nígbà tí OLUWA rí i pé Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó fún Lea ní ọmọ bí, ṣugbọn Rakẹli yàgàn. Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.” Ó tún lóyún, ó tún bí ọkunrin, ó ní, “Nítorí pé OLUWA ti gbọ́ pé wọ́n kórìíra mi ni ó ṣe fún mi ní ọmọ yìí pẹlu.” Ó bá sọ ọ́ ní Simeoni. Ó tún lóyún, ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Ọkọ mi gbọdọ̀ faramọ́ mi wàyí, nítorí pé ó di ọkunrin mẹta tí mo bí fún un”, nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Lefi. Ó tún lóyún ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Wàyí o, n óo yin OLUWA,” ó bá sọ ọ́ ní Juda. Lẹ́yìn rẹ̀, kò bímọ mọ́.