Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela:
Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Ṣela si wà ni ọgbọ̀n ọdún, o si bí Eberi:
Ṣela si wà ni irinwo ọdún o le mẹta lẹhin ti o bí Eberi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Eberi si wà li ọgbọ̀n ọdún o le mẹrin, o si bí Pelegi:
Eberi si wà ni irinwo ọdún o le ọgbọ̀n lẹhin igbati o bí Pelegi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Pelegi si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bì Reu:
Pelegi si wà ni igba ọdún o le mẹsan lẹhin igbati o bí Reu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Reu si wà li ọgbọ̀n ọdún o le meji, o si bí Serugu:
Reu si wà ni igba ọdún o le meje, lẹhin igbati o bí Serugu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Serugu si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bí Nahori:
Serugu si wà ni igba ọdún, lẹhin igba ti o bí Nahori tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Nahori si jẹ ẹni ọdún mọkandínlọgbọ̀n o si bí Tera:
Nahori si wà li ọgọfa ọdún o dí ọkan, lẹhin igbati o bí Tera tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
Tera si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Abramu, Nahori, ati Harani.
Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti.
Harani si kú ṣaju Tera baba rẹ̀, ni ilẹ ibi rẹ̀, ni Uri ti Kaldea.
Ati Abramu ati Nahor si fẹ aya fun ara wọn: orukọ aya Abramu ni Sarai; ati orukọ aya Nahori ni Milka, ọmọbinrin Harani, baba Milka, ati baba Iska.
Ṣugbọn Sarai yàgan; kò li ọmọ.