Gẹn 11:11-30
Gẹn 11:11-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela: Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Ṣela si wà ni ọgbọ̀n ọdún, o si bí Eberi: Ṣela si wà ni irinwo ọdún o le mẹta lẹhin ti o bí Eberi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Eberi si wà li ọgbọ̀n ọdún o le mẹrin, o si bí Pelegi: Eberi si wà ni irinwo ọdún o le ọgbọ̀n lẹhin igbati o bí Pelegi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Pelegi si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bì Reu: Pelegi si wà ni igba ọdún o le mẹsan lẹhin igbati o bí Reu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Reu si wà li ọgbọ̀n ọdún o le meji, o si bí Serugu: Reu si wà ni igba ọdún o le meje, lẹhin igbati o bí Serugu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Serugu si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bí Nahori: Serugu si wà ni igba ọdún, lẹhin igba ti o bí Nahori tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Nahori si jẹ ẹni ọdún mọkandínlọgbọ̀n o si bí Tera: Nahori si wà li ọgọfa ọdún o dí ọkan, lẹhin igbati o bí Tera tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Tera si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Abramu, Nahori, ati Harani. Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti. Harani si kú ṣaju Tera baba rẹ̀, ni ilẹ ibi rẹ̀, ni Uri ti Kaldea. Ati Abramu ati Nahor si fẹ aya fun ara wọn: orukọ aya Abramu ni Sarai; ati orukọ aya Nahori ni Milka, ọmọbinrin Harani, baba Milka, ati baba Iska. Ṣugbọn Sarai yàgan; kò li ọmọ.
Gẹn 11:11-30 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí Ṣemu bí Apakiṣadi tán, ó tún gbé ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Apakiṣadi di ẹni ọdún marundinlogoji ni ó bí Ṣela. Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Ṣela di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi. Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Eberi di ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn ni ó bí Pelegi. Eberi tún gbé ojilenirinwo ó dín mẹ́wàá (430) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Pelegi tán, ó tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Pelegi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu. Ó tún gbé igba ọdún ó lé mẹsan-an (209) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Reu di ẹni ọdún mejilelọgbọn ni ó bí Serugi. Ó tún gbé igba ọdún ó lé meje (207) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Serugi, ó sì tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori. Ó tún gbé igba (200) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra. Ó tún gbé igba ọdún ó lé mọkandinlogun (219) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani. Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti. Harani kú ṣáájú Tẹra, baba rẹ̀, Uri ìlú rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea ni ó kú sí. Abramu ati Nahori ní iyawo, Sarai ni orúkọ iyawo Abramu, orúkọ iyawo ti Nahori sì ni Milika, ọmọbinrin Harani. Harani ni baba Milika ati Isika. Àgàn ni Sarai, kò bímọ.
Gẹn 11:11-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùn-dínlógójì (35) ni ó bí Ṣela. Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Eberi. Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pelegi. Eberi sì wà láààyè fún irínwó ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Reu. Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ó-lé-mẹ́sàn án ọdún (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni ó bí Serugu. Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Nahori. Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹra. Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn-dínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Abramu, Nahori àti Harani. Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani, Harani sì bí Lọti. Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea. Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska. Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ.