Gal 4:28-31

Gal 4:28-31 YBCV

Njẹ ará, ọmọ ileri li awa gẹgẹ bi Isaaki. Ṣugbọn bi eyiti a bí nipa ti ara ti ṣe inunibini nigbana si eyiti a bí nipa ti Ẹmi, bẹ̃ si ni nisisiyi. Ṣugbọn iwe-mimọ́ ha ti wi? Lé ẹrú-binrin na jade ati ọmọ rẹ̀: nitori ọmọ ẹrú-binrin kì yio ba ọmọ omnira-obinrin jogun pọ̀. Nitorina, ará, awa kì iṣe ọmọ ẹrú-binrin, bikoṣe ti omnira-obinrin.