GALATIA 4:28-31

GALATIA 4:28-31 YCE

Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín. Ṣugbọn bí ó ti rí látijọ́, tí ọmọ tí a bí nípa ìfẹ́ ara ń ṣe inúnibíni ọmọ tí a bí nípa Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di ìsinsìnyìí. Ṣugbọn kí ni Ìwé Mímọ́ wí? Ó ní, “Lé ẹrubinrin ati ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrubinrin kò ní bá ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira pín ogún baba wọn.” Nítorí náà, ará, a kì í ṣe ọmọ ẹrubinrin, ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira ni wá.