Esek 42

42
1O si mu mi wá si agbala ode, li ọ̀na apa ariwa: o si mu mi wá si yará ti o kọju si ibi ti a yà sọtọ̀, ti o si kọju si ile lọna ariwa.
2Niwaju, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn ni ilẹkun ariwa, ati ibú rẹ̀ ãdọta igbọnwọ.
3Niwaju, ogún igbọnwọ ti o wà fun agbalá ti inu, ati niwaju itẹle ti o wà fun agbalá ti ode; ibujoko oke ti o kọju si ibujoko-oke wà ni orule mẹta.
4Ati niwaju awọn yará ni irìn igbọnwọ mẹwa ni ibú ninu, ọ̀na igbọnwọ kan; ilẹkùn wọn si wà nihà ariwa.
5Ati awọn yará oke kuru jù; nitori ibujoko ti awọn yará isalẹ ati yará ãrin yọ siwaju wọnyi ti ile.
6Nitori nwọn jẹ olorule mẹta, ṣugbọn nwọn kò ni ọwọ̀n bi ọwọ̀n agbalá: nitorina a fasẹhin kuro ninu yará isalẹ ati kuro ninu yará ãrin lati ilẹ wá.
7Ati ogiri ti o wà lode ti o kọju si yará, li apa agbala ode niwaju yará, gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ.
8Nitori gigùn awọn yará ti o wà lode jẹ ãdọta igbọnwọ: si wò o, niwaju tempili o jẹ ọgọrun igbọnwọ.
9Ati lati isalẹ yará wọnyi ni iwọle li ọ̀na ila-õrun wà, bi a ti nlọ sinu wọn lati agbala ode wá.
10Ni ibú ogiri agbala, li ọ̀na ila-õrun niwaju ibiti a yà sọtọ̀, ati niwaju ile na, ni awọn yará na wà.
11Ati ọ̀na iwaju wọn ti gẹgẹ bi iri awọn yará ti o wà li ọ̀na ariwa, bi nwọn ti gùn mọ, bẹ̃ ni nwọn gbòro mọ: ati gbogbo ijade wọn si dabi iṣe wọn, ati bi ilẹkùn wọn.
12Bẹ̃ gẹgẹ ni yará ti on ti ilẹkùn wọn li ọ̀na gusu, ilẹkùn kan wà lori ọ̀na, li ọ̀na gbọran niwaju ogiri li ọ̀na ila-õrun bi a ti nwọ̀ inu wọn.
13O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́.
14Nigbati awọn alufa ba wọ̀ ibẹ̀, nwọn kì yio si kuro ni ibi mimọ́ si agbala ode, ṣugbọn nibẹ nibiti nwọn gbe nṣiṣẹ ni nwọn o fi ẹwù wọn si; nitori nwọn jẹ mimọ́; nwọn o si wọ̀ ẹwù miran, nwọn o si sunmọ nkan wọnni ti o jẹ́ ti enia.
15Nigbati o si ti wọ̀n ile ti inu tan, o mu mi wá sihà ilẹkùn ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si wọ̀n yika.
16O fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ila-õrun, ẹ̃dẹgbẹta ije, nipa ije iwọ̀nlẹ yika.
17O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ariwa, ẹ̃dẹgbẹta ije yika.
18O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa gusu, ẹ̃dẹgbẹta ije.
19O yipadà si ọ̀na iwọ-õrun, o si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ọ, ẹ̃dẹgbẹta ije.
20O wọ̀n ọ nihà mẹrẹrin: o ni ogiri kan yi i ka, ẹ̃dẹgbẹta ije ni gigùn, ati ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, lati pàla lãrin ibi mimọ́ ati ibi aimọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek 42: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀