Esek 41
41
1O si mu mi wá si tempili, o si wọ̀n awọn atẹrigbà, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakan, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakeji, ibú agọ na.
2Ati ibú ilẹkùn na jẹ igbọnwọ mẹwa; ihà ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ marun li apakan, ati igbọnwọ marun li apakeji; o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogoji igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ.
3O si wá si inu rẹ̀, o si wọ̀n atẹrigbà ilẹkùn na, igbọnwọ meji; ati ilẹkùn na, igbọnwọ mẹfa; ibú ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ meje.
4Bẹ̃ li o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogún igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ, niwaju tempili: o si wi fun mi pe, Eyi ni ibi mimọ́ julọ.
5O si wọ̀n ogiri ile na, igbọnwọ mẹfa; ati ibú yàrá-ihà gbogbo igbọnwọ mẹrin, yi ile na ka nihà gbogbo.
6Ati awọn yará-ihà, ọkan lori ekeji jẹ mẹta, nigba ọgbọ̀n: nwọn si wọ̀ inu ogiri ti ile awọn yará-ihà na yika, ki nwọn ba le di ara wọn mu, nitori kò si idimú ninu ogiri ile na.
7A si ṣe e gborò, o si lọ yika loke awọn yará ihà: nitori ogiri ile na lọ loke-loke yi ile na ka: nitorina ibú ile na wà loke, bẹ̃ni iyará isalẹ yọ si toke lãrin.
8Emi si ri giga ile na yika: ipilẹ awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na si jẹ ije kikun kan ti igbọnwọ mẹfa ni gigun.
9Ibú ogiri na, ti yará-ẹ̀gbẹ́ lode, jẹ igbọnwọ marun: ati eyi ti o kù ni ibi yará-ẹ̀gbẹ́ ti mbẹ ninu.
10Ati lãrin yará na, ogún igbọnwọ ni gbigborò, yi ile na ka ni ihà gbogbo.
11Ati ilẹkùn awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na mbẹ li ọ̀na ibi ti o kù, ilẹkùn kan li ọ̀na ariwa, ati ilẹkùn kan ni gusu: ati ibú ibẹ̀ na ti o kù, jẹ igbọnwọ marun yika.
12Ati ile ti o wà niwaju eyiti a yà sọtọ̀ ni igun ọ̀na iwọ-õrun, jẹ ãdọrin igbọnwọ ni gbigborò; ogiri ile na si jẹ igbọnwọ marun ni ibú yika, ati gigùn rẹ̀, ãdọrun igbọnwọ.
13O si wọ̀n ile na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn; ati ibi ti a yà sọtọ̀, ati ile na, pẹlu ogiri wọn, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn.
14Ati ibú oju ile na, ati ti ibi ti a yà sọtọ̀ nihà ila-õrun ọgọrun igbọnwọ.
15O si wọ̀n gigun ile na ti o kọju si ibiti a yà sọtọ̀ ti mbẹ lẹhin rẹ̀, ati ibujoko-oke ni ihà kan ati nihà miran, ọgọrún igbọnwọ, pẹlu tempeli inu, ati iloro agbalá na;
16Awọn iloro, ati ferese toro, ati ibujoko oke yika lori ile olorule mẹta wọn, ti o wà niwaju iloro na, li a fi igi tẹ́ yika, ati lati ilẹ de oke ferese, a si bò awọn ferese na;
17Si ti oke ilẹkun ani titi de ile ti inu, ati ti ode, ati lara ogiri niha gbogbo tinu tode ni wiwọ̀n.
18Kerubu ati igi ọpẹ li a si fi ṣe e, igi ọpẹ kan si mbẹ lãrin kerubu ati kerubu: kerubu kọkan si ni oju meji;
19Oju enia kan si wà nihà ibi igi ọpe li apa kan, ati oju ẹgbọ̀rọ kiniun kan si wà nihà ibi igi ọpẹ li apa keji: a ṣe e yi ile na ka niha gbogbo.
20Lati ilẹ titi fi de okè ilẹkùn, ni a ṣe kerubu ati igi ọpẹ si, ati lara ogiri tempili na.
21Awọn opó ilẹkùn tempili na jẹ igun mẹrin lọgbọgba: ati iwaju ibi mimọ́ irí ọkan bi irí ekeji.
22Pẹpẹ igi na jẹ igbọnwọ mẹta ni giga, gigùn rẹ̀ igbọnwọ meji; ati igun rẹ̀, ati gigùn rẹ̀, ati awọn ogiri rẹ̀ jẹ ti igi: o si wi fun mi pe, Eyi ni tabili ti mbẹ niwaju Oluwa.
23Ati tempili na, ati ibi mimọ́ na, ni ilẹkùn meji.
24Awọn ilẹkùn mejeji na ni awẹ, awẹ meji ti nyi; awẹ meji fun ilẹkùn kan, ati awẹ meji fun ilẹkùn keji.
25Kerubu, ati igi ọpẹ li a ṣe si ara wọn, sara ilẹkùn tempili, gẹgẹ bi eyiti a ṣe sara ogiri; igi ibori wà loju iloro lode.
26Ferese toro ati igi ọpẹ mbẹ nihà ihin ati nihà ọhun nihà iloro, ati ni yará-iha ile na, ati ni igi ibori.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 41: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.