O tun wi fun mi pe, Sọtẹlẹ sori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, Ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa.
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ̀ inu nyin, ẹnyin o si yè:
Emi o si fi iṣan sara nyin, emi o si mu ẹran wá sara nyin, emi o si fi àwọ bò nyin, emi o si fi ẽmi sinu nyin, ẹnyin o si yè; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Bẹ̃ni mo ṣotẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi: bi mo si ti sọtẹlẹ, ariwo ta, si wò o, mimì kan wà, awọn egungun na si wá ọdọ ara wọn, egungun si egungun rẹ̀.
Nigbati mo si wò, kiyesi i, iṣan ati ẹran-ara wá si wọn, àwọ si bò wọn loke: ṣugbọn ẽmi kò si ninu wọn.
Nigbana li o sọ fun mi, pe, ọmọ enia, Sọtẹlẹ si ẽmi, sọtẹlẹ, si wi fun ẽmi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ ẽmi, wá lati igun mẹrẹrin, si mí si okú wọnyi, ki nwọn ba le yè.
Bẹ̃ni mo sọtẹlẹ gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun mi, ẽmi na si wá sinu wọn, nwọn si yè, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn ogun nlanla.