Ó bá sọ fún mi pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn egungun wọnyi, kí o wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ wọnyi, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí’. Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè. N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Bí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí so mọ́ ara wọn; egungun ń so mọ́ egungun. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, iṣan ti dé ara wọn, ẹran ti bo iṣan, awọ ara sì ti bò wọ́n, ṣugbọn kò tíì sí èémí ninu wọn. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún èémí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Wá, ìwọ èémí láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé, kí o fẹ́ sinu àwọn òkú wọnyi, kí wọ́n di alààyè.’ ” Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ó ti pàṣẹ fún mi. Èémí wọ inú wọn, wọ́n sì di alààyè; ogunlọ́gọ̀ eniyan ni wọ́n, wọ́n bá dìde dúró!
Kà ISIKIẸLI 37
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ISIKIẸLI 37:4-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò