Esek 31

31
1O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kẹta, li ọjọ ekini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, sọ fun Farao ọba Egipti, ati fun ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ pe, Tani iwọ jọ ni titobi rẹ?
3Kiyesi i, awọn ara Assiria ni igi kedari ni Lebanoni ti o li ẹ̀ka daradara, ti o si ṣiji boni, ti o si ga, ṣonṣo ori rẹ̀ si wà lãrin awọn ẹ̀ka bibò.
4Omi sọ ọ di nla, ibú gbé e ga soke, o fi awọn odò nla rẹ̀ yi oko rẹ̀ ka, o si rán awọn odo kékèké rẹ̀ si gbogbo igbẹ́.
5Nitorina a gbe giga rẹ̀ soke jù gbogbo igi igbẹ́ lọ, ẹ̀ka rẹ̀ si di pupọ̀, awọn ẹ̀ka rẹ̀ si di gigùn nitori ọ̀pọlọpọ omi, nigbati o yọ wọn jade.
6Gbogbo ẹiyẹ oju ọrun kọ́ itẹ́ wọn ninu ẹ̀ka rẹ̀, ati labẹ ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ bi ọmọ wọn si, ati labẹ ojiji rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ède nla ngbe.
7Bayi li o ni ẹwà ninu titobi rẹ̀, ninu gigùn ẹ̀ka rẹ̀: nitori ti egbò rẹ̀ wà li ẹbá omi nla.
8Awọn igi kedari inu ọgbà Ọlọrun kò le bò o mọlẹ: awọn igi firi kò dabi ẹ̀ka rẹ̀, awọn igi kẹsnuti kò si dabi ẹ̀ka rẹ̀; bẹ̃ni kò si igikigi ninu ọgbà Ọlọrun ti o dabi rẹ̀ li ẹwà rẹ̀.
9Emi ti ṣe e ni ẹwà nipa ọ̀pọlọpọ ẹ̀ka rẹ̀: tobẹ̃ ti gbogbo igi Edeni, ti o wà ninu ọgbà Ọlọrun, ṣe ilara rẹ̀.
10Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti on gbe ara rẹ̀ soke ni giga, o si ti yọ ṣonṣo rẹ̀ soke lãrin awọn ẹ̀ka didí, ọkàn rẹ̀ si gbe soke nitori giga rẹ̀;
11Nitorina li emi ti ṣe fi i le alagbara awọn keferi lọwọ; on o bá a ṣe dajudaju: Emi ti lé e jade nitori buburu rẹ̀.
12Ati awọn alejo, ẹlẹ́rù awọn orilẹ-ède, ti ké e kuro, nwọn si ti tú u ká; ẹka rẹ̀ ṣubu sori awọn oke, ati ninu gbogbo afonifoji, ẹka rẹ̀ si ṣẹ́ lẹba gbogbo odò ilẹ na; gbogbo awọn orilẹ-ède aiye si jade lọ kuro labẹ òjiji rẹ̀, nwọn si fi i silẹ.
13Gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun yio ma gbe ori ahoro rẹ̀, ati lori ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ yio wà.
14Nitori ki igikigi ti o wà lẹba omi ki o má ba gbe ara wọn ga nitori giga wọn, tabi ki nwọn yọ ṣonṣo wọn lãrin ẹ̀ka dídi; tabi ki igi wọn duro ni giga wọn, gbogbo awọn ti o mu omi: nitori ti a fi gbogbo wọn le ikú lọwọ, si isalẹ aiye, li ãrin awọn ọmọ enia, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.
15Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pe, Li ọjọ ti o sọkalẹ lọ si ibojì mo jẹ ki ọ̀fọ ki o wà, mo fi ibú bò o mọlẹ, mo si se awọn iṣàn omi, awọn omi nla ni mo si dá duro: emi si jẹ ki Lebanoni ki o ṣọ̀fọ fun u, gbogbo igi igbẹ́ si dakú nitori rẹ̀.
16Emi mu awọn orilẹ̀-èdè mì nipa iró iṣubu rẹ̀, nigbati mo sọ ọ sinu ipòokú, pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, ati gbogbo igi Edeni, awọn àṣayan ati awọn ti o dara jù ti Lebanoni, gbogbo awọn ti o mu omi, li a o tù ninu ni ìsalẹ aiye.
17Awọn pẹlu sọkalẹ lọ sinu ipò-okú pẹlu rẹ̀ sọdọ awọn ti a fi idà pa; awọn ti o si jẹ apá rẹ̀, ti ngbe abẹ òjiji rẹ̀ li ãrin awọn keferi.
18Tani iwọ jọ li ogo ati ni titobi lãrin awọn igi Edeni? sibẹ a o mu ọ wá ilẹ pẹlu awọn igi Edeni si ìsalẹ aiye, iwọ o dubulẹ li ãrin awọn alaikọlà, pẹlu awọn ti a fi idà pa. Eyi ni Farao ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek 31: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀