Esek 30

30
1Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, sọtẹlẹ ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹ wu, Egbé fun ọjọ na!
3Nitori ọjọ na sunmọ tosí, ani ọjọ Oluwa sunmọ tosi, ọjọ ikũkũ ni; yio jẹ akoko ti awọn keferi.
4Idà yio si wá sori Egipti, irora nla yio wà ni Etiopia, nigbati awọn ti a pa yio ṣubu ni Egipti, nwọn o si mu ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ lọ kuro, ipilẹ rẹ̀ yio si wó lulẹ.
5Etiopia, ati Libia, ati Lidia, ati gbogbo awọn olùranlọ́wọ, ati Kubu, ati awọn enia ilẹ na ti o mulẹ yio ti ipa idà ṣubu pẹlu wọn.
6Bayi li Oluwa wi; Awọn pẹlu ti nwọn gbe Egipti ró yio ṣubu; ati igberaga agbara rẹ̀ yio sọkalẹ: lati Migdoli lọ de Siene ni nwọn o ti ipà idà ṣubu ninu rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.
7Nwọn o si di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ilu rẹ̀ yio si wà li àrin awọn ilu ti o di ahoro.
8Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo bá gbe iná kalẹ ni Egipti, ti gbogbo awọn olùranlọ́wọ rẹ̀ bá parun.
9Li ọjọ na ni onṣẹ yio lọ lati ọdọ mi ninu ọkọ̀, lati dẹ̀ruba Etiopia ti o wà li alafia, irora yio wá sori wọn gẹgẹ bi li ọjọ Egipti: kiyesi i, o de.
10Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si ṣe ki ọ̀pọlọpọ enia Egipti ki o ti ipa ọwọ́ Nebukaddressari ọba Babiloni dínkù.
11On ati enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹ̀ru awọn orilẹ-ède, li a o mu wá pa ilẹ na run: nwọn o si fà idà wọn yọ si Egipti, nwọn o si fi awọn ti a pa kún ilẹ na.
12Emi o mu gbogbo odò wọn gbẹ, emi o si tà ilẹ na si ọwọ́ awọn enia buburu; emi o si ti ipa ọwọ́ awọn alejo sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹkún rẹ̀: Emi Oluwa li o ti sọ ọ.
13Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o pa awọn oriṣa run pẹlu, emi o si jẹ ki ere wọn tán ni Nofi; kì yio si si ọmọ alade kan ni ilẹ Egipti mọ́: emi o si fi ẹ̀ru si ilẹ Egipti.
14Emi o si sọ Patrosi di ahoro, emi o si gbe iná kalẹ ni Soani, emi o si mu idajọ ṣẹ ni No.
15Emi o si dà irúnu mi si ori Sini, agbara Egipti; emi o si ké ọ̀pọlọpọ enia No kuro.
16Emi o si gbe iná kalẹ ni Egipti, Sini yio ni irora nla, a o si fà No ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, Nofi yio si ni ipọnju lojojumọ.
17Awọn ọdọmọkunrin Afeni ati Pibeseti yio ti ipa idà ṣubu: ati awọn wọnyi yio lọ si igbèkun.
18Ọjọ yio si ṣõkun ni Tehafnehesi, nigbati emi bá dá àjaga ọrùn Egipti nibẹ: ọṣọ́ agbara rẹ̀ yio tán ninu rẹ̀: bi o ṣe tirẹ̀ ni, ikũkũ yio bò on, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin yio lọ si igbèkun.
19Bayi li emi o mu idajọ ṣẹ ni Egipti: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
20O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kini, li ọjọ keje oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
21Ọmọ enia, emi ti ṣẹ apá Farao ọba Egipti; si kiyesi i, a kì yio dì i ki o ba le san, bẹ̃ni a kì yio fi igi si i lati dì i ki o ba lagbara lati di idà mu.
22Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, emi dojukọ Farao ọba Egipti, emi o si ṣẹ́ apá rẹ̀, eyi ti o le, ati eyiti o ṣẹ́; emi o si jẹ ki idà bọ́ kuro li ọwọ́ rẹ̀.
23Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin ilẹ.
24Emi o si mu apá ọba Babiloni le, emi o si fi idà mi si ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn emi o ṣẹ́ apá Farao, yio si ma kerora niwaju rẹ bi ikérora ọkunrin ti a ṣá li aṣápa.
25Ṣugbọn emi o mu apá ọba Babiloni le, apá Farao yio si rọ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ba fi idà mi si ọwọ́ ọba Babiloni, ki o le ba nà a sori ilẹ Egipti.
26Emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin awọn orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin awọn ilẹ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek 30: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀