O si ṣe ọgbọ̀n ọdun, ni oṣu ẹkẹrin, li ọjọ ẹkarun oṣu, bi mo ti wà lãrin awọn igbekùn leti odo Kebari, ọrun ṣi, mo si ri iran Ọlọrun.
Li ọjọ karun oṣu, ti iṣe ọdun karun igbekùn Jehoiakini ọba,
Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Esekieli alufa, ọmọ Busi wá papã, ni ilẹ awọn ara Kaldea leti odò Kebari, ọwọ́ Oluwa si wà li ara rẹ̀ nibẹ.
Mo si wò, si kiye si i, ãja jade wá lati ariwa, awọsanma nla, ati iná ti o yi ara rẹ̀ ka, didán si wà yika, ani lati ãrin rẹ̀ wá, bi àwọ amberi, lati ãrin iná na wá.
Pẹlupẹlu lati ãrin rẹ̀ wá, aworan ẹda alãye mẹrin, eyi si ni irí wọn, nwọn ni aworan enia.
Olukuluku si ni oju mẹrin, olukuluku si ni iyẹ mẹrin.
Ẹsẹ wọn si tọ́, atẹlẹsẹ wọn si dabi atẹlẹsẹ ọmọ malũ: nwọn si tàn bi awọ̀ idẹ didan.
Nwọn si ni ọwọ́ enia labẹ iyẹ́ wọn, li ẹgbẹ wọn mẹrẹrin, awọn mẹrẹrin si ni oju wọn ati iyẹ́ wọn.
Iyẹ́ wọn si kàn ara wọn; nwọn kò yipada nigbati nwọn lọ, olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran.
Niti aworan oju wọn, awọn mẹrẹrin ni oju enia, ati oju kiniun, niha ọtun: awọn mẹrẹrin si ni oju malu niha osì; awọn mẹrẹrin si ni oju idì.
Bayi li oju wọn ri: iyẹ́ wọn si nà soke, iyẹ́ meji olukuluku wọn kàn ara wọn, meji si bo ara wọn.
Olukuluku wọn si lọ li ọkankan ganran: nibiti ẹmi ibá lọ, nwọn lọ; nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ.
Niti aworan awọn ẹda alãye na, irí wọn dabi ẹṣẹ́ iná, ati bi irí inà fitila: o lọ soke ati sodo, lãrin awọn ẹda alãye na, iná na si mọlẹ, manamana si jade lati inu iná na wá.
Awọn ẹda alãye na si sure, awọn si pada bi kíkọ manamana.
Bi mo si ti wo awọn ẹda alãye na, kiyesi i, kẹkẹ́ kan wà lori ilẹ aiye lẹba awọn ẹda alãye na, pẹlu oju rẹ̀ mẹrin.
Irí awọn kẹkẹ́ na ati iṣẹ wọn dabi awọ̀ berili: awọn mẹrẹrin ni aworan kanna; irí wọn ati iṣẹ wọn dabi ẹnipe kẹkẹ́ li ãrin kẹkẹ́.
Nigbati nwọn lọ, nwọn fi iha wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ.
Niti oruka wọn, nwọn ga tobẹ̃ ti nwọn fi ba ni li ẹ̀ru; oruka wọn si kún fun oju yi awọn mẹrẹrin ka.
Nigbati awọn ẹda alãye na lọ, awọn kẹkẹ́ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati a si gbe awọn ẹda alãye na soke, kuro lori ilẹ, a gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu.
Nibikibi ti ẹmi ni iba lọ, nwọn lọ; nibẹ li ẹmi fẹ ilọ: a si gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu wọn; nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na.
Nigbati wọnni lọ, wọnyi lọ; nigbati a gbe wọnni duro, wọnyi duro; ati nigbati a gbe wọnni soke kuro lori ilẹ a gbe kẹkẹ́ soke pẹlu wọn: nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na.
Aworan ofurufu li ori ẹda alãye na dabi àwọ kristali ti o ba ni li ẹ̀ru, ti o nà sori wọn loke.
Iyẹ́ wọn si tọ́ labẹ ofurufu, ekini si ekeji: olukuluku ni meji, ti o bo ihà ihín, olukuluku si ni meji ti o bo iha ọhún ara wọn.
Nigbati nwọn si lọ, mo gbọ́ ariwo iyẹ́ wọn, bi ariwo omi pupọ, bi ohùn Olodumare, ohùn ọ̀rọ bi ariwo ogun: nigbati nwọn duro, nwọn rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ.
Ohùn kan ti inu ofurufu ti o wà lori wọn wá, nigbati nwọn duro, ti nwọn si ti rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ.
Ati lori ofurufu ti o wà lori wọn, aworan itẹ kan wà, bi irí okuta safire: ati loke aworan itẹ na li aworan kan bi ori enia wà.
Mo si ri bi awọ amberi, bi irí iná yika ninu rẹ̀, lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de oke, ati lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de isalẹ, mo ri bi ẹnipe irí iná, o si ni didan yika.
Bi irí oṣumare ti o wà ninu awọsanma ni ọjọ ojo, bẹ̃ni irí didan na yika. Eyi ni aworan ogo Oluwa. Nigbati mo si ri, mo dojubolẹ, mo si gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọ̀rọ.