Esek 1:1-28

Esek 1:1-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe ọgbọ̀n ọdun, ni oṣu ẹkẹrin, li ọjọ ẹkarun oṣu, bi mo ti wà lãrin awọn igbekùn leti odo Kebari, ọrun ṣi, mo si ri iran Ọlọrun. Li ọjọ karun oṣu, ti iṣe ọdun karun igbekùn Jehoiakini ọba, Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Esekieli alufa, ọmọ Busi wá papã, ni ilẹ awọn ara Kaldea leti odò Kebari, ọwọ́ Oluwa si wà li ara rẹ̀ nibẹ. Mo si wò, si kiye si i, ãja jade wá lati ariwa, awọsanma nla, ati iná ti o yi ara rẹ̀ ka, didán si wà yika, ani lati ãrin rẹ̀ wá, bi àwọ amberi, lati ãrin iná na wá. Pẹlupẹlu lati ãrin rẹ̀ wá, aworan ẹda alãye mẹrin, eyi si ni irí wọn, nwọn ni aworan enia. Olukuluku si ni oju mẹrin, olukuluku si ni iyẹ mẹrin. Ẹsẹ wọn si tọ́, atẹlẹsẹ wọn si dabi atẹlẹsẹ ọmọ malũ: nwọn si tàn bi awọ̀ idẹ didan. Nwọn si ni ọwọ́ enia labẹ iyẹ́ wọn, li ẹgbẹ wọn mẹrẹrin, awọn mẹrẹrin si ni oju wọn ati iyẹ́ wọn. Iyẹ́ wọn si kàn ara wọn; nwọn kò yipada nigbati nwọn lọ, olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran. Niti aworan oju wọn, awọn mẹrẹrin ni oju enia, ati oju kiniun, niha ọtun: awọn mẹrẹrin si ni oju malu niha osì; awọn mẹrẹrin si ni oju idì. Bayi li oju wọn ri: iyẹ́ wọn si nà soke, iyẹ́ meji olukuluku wọn kàn ara wọn, meji si bo ara wọn. Olukuluku wọn si lọ li ọkankan ganran: nibiti ẹmi ibá lọ, nwọn lọ; nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ. Niti aworan awọn ẹda alãye na, irí wọn dabi ẹṣẹ́ iná, ati bi irí inà fitila: o lọ soke ati sodo, lãrin awọn ẹda alãye na, iná na si mọlẹ, manamana si jade lati inu iná na wá. Awọn ẹda alãye na si sure, awọn si pada bi kíkọ manamana. Bi mo si ti wo awọn ẹda alãye na, kiyesi i, kẹkẹ́ kan wà lori ilẹ aiye lẹba awọn ẹda alãye na, pẹlu oju rẹ̀ mẹrin. Irí awọn kẹkẹ́ na ati iṣẹ wọn dabi awọ̀ berili: awọn mẹrẹrin ni aworan kanna; irí wọn ati iṣẹ wọn dabi ẹnipe kẹkẹ́ li ãrin kẹkẹ́. Nigbati nwọn lọ, nwọn fi iha wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ. Niti oruka wọn, nwọn ga tobẹ̃ ti nwọn fi ba ni li ẹ̀ru; oruka wọn si kún fun oju yi awọn mẹrẹrin ka. Nigbati awọn ẹda alãye na lọ, awọn kẹkẹ́ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati a si gbe awọn ẹda alãye na soke, kuro lori ilẹ, a gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu. Nibikibi ti ẹmi ni iba lọ, nwọn lọ; nibẹ li ẹmi fẹ ilọ: a si gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu wọn; nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na. Nigbati wọnni lọ, wọnyi lọ; nigbati a gbe wọnni duro, wọnyi duro; ati nigbati a gbe wọnni soke kuro lori ilẹ a gbe kẹkẹ́ soke pẹlu wọn: nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na. Aworan ofurufu li ori ẹda alãye na dabi àwọ kristali ti o ba ni li ẹ̀ru, ti o nà sori wọn loke. Iyẹ́ wọn si tọ́ labẹ ofurufu, ekini si ekeji: olukuluku ni meji, ti o bo ihà ihín, olukuluku si ni meji ti o bo iha ọhún ara wọn. Nigbati nwọn si lọ, mo gbọ́ ariwo iyẹ́ wọn, bi ariwo omi pupọ, bi ohùn Olodumare, ohùn ọ̀rọ bi ariwo ogun: nigbati nwọn duro, nwọn rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ. Ohùn kan ti inu ofurufu ti o wà lori wọn wá, nigbati nwọn duro, ti nwọn si ti rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ. Ati lori ofurufu ti o wà lori wọn, aworan itẹ kan wà, bi irí okuta safire: ati loke aworan itẹ na li aworan kan bi ori enia wà. Mo si ri bi awọ amberi, bi irí iná yika ninu rẹ̀, lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de oke, ati lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de isalẹ, mo ri bi ẹnipe irí iná, o si ni didan yika. Bi irí oṣumare ti o wà ninu awọsanma ni ọjọ ojo, bẹ̃ni irí didan na yika. Eyi ni aworan ogo Oluwa. Nigbati mo si ri, mo dojubolẹ, mo si gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọ̀rọ.

Esek 1:1-28 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹrin, ní ọgbọ̀n ọdún, èmi, Isikiẹli, ọmọ Busi, wà láàrin àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Babiloni. A wà lẹ́bàá odò Kebari, mo bá rí i tí ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀; mo sì rí ìran Ọlọrun. Lọ́jọ́ karun-un oṣù náà, tíí ṣe ọdún karun-un tí wọ́n ti mú ọba Jehoiakini lọ sí ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea lẹ́bàá odò Kebari; agbára OLUWA sì sọ̀kalẹ̀ sí mi lára. Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà. Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin. Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ. Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin. Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ. Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn. Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora. Olukuluku kọjú sí ìhà mẹrin, ó sì lè lọ tààrà sí ìhà ibi tí ẹ̀mí rẹ̀ bá darí sí láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada kí ó tó máa lọ. Nǹkankan wà láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè náà tí ó dàbí ẹ̀yinná tí ń jó. Ó ń lọ sókè sódò láàrin wọn bí ahọ́n iná. Iná náà mọ́lẹ̀, ó sì ń kọ mànàmànà. Àwọn ẹ̀dá alààyè náà ń já lọ sókè sódò bí ìgbà tí manamana bá ń kọ. Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, àgbá kọ̀ọ̀kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà ati bí a ti ṣe wọ́n nìyí: wọ́n ń dán yànrànyànràn bí òkúta kirisolite. Bákan náà ni àwọn mẹrẹẹrin rí. A ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí ìgbà tí àgbá meji bá wọ inú ara wọn. Bí wọ́n ti ń lọ, ìhà ibi tí wọn bá fẹ́ ninu ìhà mẹrẹẹrin ni wọ́n lè máa lọ láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yíjú pada, kí wọ́n tó máa lọ. (Àgbá mẹrẹẹrin ní irin tẹẹrẹtẹẹrẹ tí ó so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọ̀). Wọ́n ga, wọ́n ba eniyan lẹ́rù. Àwọn àgbá mẹrẹẹrin ní ojú yíká wọn. Bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ti ń lọ ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a máa yí tẹ̀lé wọn, bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá gbéra nílẹ̀ àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì gbéra nílẹ̀ pẹlu. Ibikíbi tí ẹ̀mí bá fẹ́ lọ ni àwọn ẹ̀dá náà máa ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a sì máa yí lọ pẹlu wọn, nítorí pé ninu àwọn àgbá náà ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà. Bí wọn bá ń lọ àwọn àgbá náà a máa yí lọ pẹlu wọn. Bí wọ́n bá dúró àwọn àgbá náà a dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn àgbá náà a gbéra nílẹ̀, nítorí pé ninu àwọn àgbá wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà. Kinní kan bí awọsanma tí ó ń dán bíi Kristali wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó tàn bo gbogbo orí wọn. Lábẹ́ kinní bí awọsanma yìí ni àwọn ìyẹ́ wọn ti nà jáde, wọ́n kan ara wọn, àwọn ẹ̀dá alààyè náà ní ìyẹ́ meji meji tí wọ́n fi bora. Bí wọ́n ti ń lọ, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn, ó dàbí ariwo odò ńlá, bí ààrá Olodumare, bí ariwo ìdágìrì ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Bí wọ́n bá dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀, nǹkankan a sì máa dún lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn. Bí wọn bá ti dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀. Mo rí kinní kan lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn, ó dàbí ìtẹ́ tí a fi òkúta safire ṣe; mo sì rí kinní kan tí ó dàbí eniyan, ó jókòó lórí nǹkankan bí ìtẹ́ náà. Mo wò ó láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó rí bíi bàbà dídán, ó dàbí iná yíká. Mo wò ó láti ibi ìbàdí lọ sí ìsàlẹ̀, ó dàbí iná. Ìmọ́lẹ̀ sì wà ní gbogbo àyíká rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ tí ó yí i ká dàbí òṣùmàrè tí ó yọ ninu ìkùukùu lákòókò òjò. Bẹ́ẹ̀ ni àfiwé ìfarahàn ògo OLUWA rí.

Esek 1:1-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrín àwọn ìgbèkùn ní etí odò Kebari, àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run. Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn ọba Jehoiakini— ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ àlùfáà Esekiẹli, ọmọ Busii wá, létí odò Kebari ni ilẹ̀ àwọn ará Babeli. Níbẹ̀ ni ọwọ́ OLúWA ti wà lára rẹ̀. Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná, àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin. Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán. Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́, ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni. Báyìí ni ìrísí ojú àwọn ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apá ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì. Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn. Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ. Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná fìtílà. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrín àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀. Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá. Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kirisoleti, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú. Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà sí ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ. Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká. Bí àwọn ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹ̀gbẹ́ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè. Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn. Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́. Ohun tí ó dàbí òfúrufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù. Ìyẹ́ wọn sì tọ́ lábẹ́ òfúrufú, èkínní sí èkejì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ méjì méjì tí ó bo ara wọn. Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀. Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n. Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà. Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká. Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká. Báyìí ni ìrísí ògo OLúWA. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa