OLUWA si wi fun Mose pe, Yà gbogbo awọn akọ́bi sọ̀tọ fun mi, gbogbo eyiti iṣe akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia, ati ti ẹran: ti emi ni iṣe. Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ ranti ọjọ́ oni, ninu eyiti ẹnyin jade kuro ni Egipti, kuro li oko-ẹrú; nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú nyin jade kuro nihin: a ki yio si jẹ àkara wiwu. Li ọjọ́ oni li ẹnyin jade li oṣù Abibu. Yio si ṣe nigbati OLUWA yio mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn enia Hitti, ati ti awọn ara Amori, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, on ni iwọ o ma sìn ìsin yi li oṣù yi. Ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, li ọjọ́ keje li ajọ yio wà fun OLUWA. Ọjọ́ meje li a o fi jẹ àkara alaiwu; ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ, bẹ̃ni ki a má si ṣe ri iwukàra lọdọ rẹ ni gbogbo ẹkùn rẹ. Iwọ o si sọ fun ọmọ rẹ li ọjọ́ na pe, A nṣe eyi nitori eyiti OLUWA ṣe fun mi nigbati mo jade kuro ni Egipti. Yio si ma ṣe àmi fun ọ li ọwọ́ rẹ, ati fun àmi iranti li agbedemeji oju rẹ, ki ofin OLUWA ki o le wà li ẹnu rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú ọ jade kuro ni Egipti. Nitorina ni ki iwọ ki o ma kiyesi ìlana yi li akokò rẹ̀ li ọdọdún.
Kà Eks 13
Feti si Eks 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 13:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò