Eks 13:1-10

Eks 13:1-10 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé, “Ya gbogbo àwọn àkọ́bí sí mímọ́ fún mi, ohunkohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn eniyan Israẹli, kì báà ṣe ti eniyan, tabi ti ẹranko, tèmi ni wọ́n.” Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí. Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu. Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ní ọjọ́ keje ẹ óo pe àpèjọ kan fún OLUWA láti ṣe àjọ̀dún. Láàrin ọjọ́ meje tí ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, a kò gbọdọ̀ rí burẹdi tí ó ní ìwúkàrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ninu yín, kò sì gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ní gbogbo agbègbè yín. Kí olukuluku wí fún ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, ‘Nítorí ohun tí OLUWA ṣe fún mi, nígbà tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe yìí.’ Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá. Nítorí náà, ẹ máa ṣe ìrántí ìlànà yìí ní àkókò rẹ̀ ní ọdọọdún.

Eks 13:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.” Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí OLúWA mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú. Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún OLúWA. Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí OLúWA ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’ Ṣíṣe èyí yóò wà fún ààmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ààmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin OLúWA ní ẹnu rẹ. Nítorí OLúWA mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀. Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.