NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ; Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si kọlù wọn; ki o si run wọn patapata; iwọ kò gbọdọ bá wọn dá majẹmu, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá wọn dá ana; ọmọbinrin rẹ ni iwọ kò gbọdọ fi fun ọmọkunrin rẹ̀, ati ọmọbinrin rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ mú fun ọmọkunrin rẹ. Nitoripe nwọn o yi ọmọkunrin rẹ pada lati ma tọ̀ mi lẹhin, ki nwọn ki o le ma sìn ọlọrun miran: ibinu OLUWA o si rú si nyin, on a si run ọ lojiji. Ṣugbọn bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bì ọwọ̀n wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn. Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.
Kà Deu 7
Feti si Deu 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 7:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò