Deu 7:1-6

Deu 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí OLúWA Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ náà, tí ìwọ yóò wọ̀ lọ láti gbà, tí ìwọ yóò sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ: Àwọn ará Hiti, Girgaṣi, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi: Àwọn orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀jù ọ lọ, nígbà tí OLúWA Ọlọ́run rẹ bá sì ti fi wọ́n lé ẹ lọ́wọ́, tí ìwọ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ìwọ kí ó sì pa wọ́n run pátápátá. Má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn. Ìwọ kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin rẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ, torí pé wọ́n yóò yí àwọn ọmọ rẹ padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú OLúWA yóò sì wá sórí rẹ, yóò sì run yín kíákíá. Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn: Ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Aṣerah wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná. Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí OLúWA Ọlọ́run yín, OLúWA Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.