Iṣe Apo 6:12-15

Iṣe Apo 6:12-15 YBCV

Nwọn si rú awọn enia soke, ati awọn àgbagba, ati awọn akọwe, nwọn dide si i, nwọn gbá a mu, nwọn mu u wá si ajọ igbimọ. Nwọn si mu awọn ẹlẹri eke wá, ti nwọn wipe, ọkunrin yi kò simi lati sọ ọ̀rọ-òdi si ibi mimọ́ yi, ati si ofin: Nitori awa gbọ́ o wipe, Jesu ti Nasareti yi yio fọ́ ibi yi, yio si pa iṣe ti Mose fifun wa dà. Ati gbogbo awọn ti o si joko ni ajọ igbimọ tẹjumọ́ ọ, nwọn nwò oju rẹ̀ bi ẹnipe oju angẹli.