Iṣe Apo 6:12-15
Iṣe Apo 6:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si rú awọn enia soke, ati awọn àgbagba, ati awọn akọwe, nwọn dide si i, nwọn gbá a mu, nwọn mu u wá si ajọ igbimọ. Nwọn si mu awọn ẹlẹri eke wá, ti nwọn wipe, ọkunrin yi kò simi lati sọ ọ̀rọ-òdi si ibi mimọ́ yi, ati si ofin: Nitori awa gbọ́ o wipe, Jesu ti Nasareti yi yio fọ́ ibi yi, yio si pa iṣe ti Mose fifun wa dà. Ati gbogbo awọn ti o si joko ni ajọ igbimọ tẹjumọ́ ọ, nwọn nwò oju rẹ̀ bi ẹnipe oju angẹli.
Iṣe Apo 6:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n sọ pé, “Ọkunrin yìí kò yé sọ̀rọ̀ lòdì sí Tẹmpili mímọ́ yìí ati sí òfin Mose. Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.” Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli.
Iṣe Apo 6:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀. Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tiwọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin. Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jesu ti Nasareti yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mose fi fún wa padà.” Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.