Ṣugbọn Peteru dide duro pẹlu awọn mọkanla iyokù, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o si wi fun wọn gbangba pe, Ẹnyin enia Judea, ati gbogbo ẹnyin ti ngbé Jerusalemu, ki eyiyi ki o yé nyin, ki ẹ si fetísi ọ̀rọ mi: Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi. Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe; Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá: Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ: Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn loke li ọrun, ati àmi nisalẹ lori ilẹ: ẹ̀jẹ, ati iná, ati ríru ẹ̃fin; A o sọ õrùn di òkunkun, ati oṣupa di ẹ̀jẹ, ki ọjọ nla afiyesi Oluwa ki o to de: Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba pè orukọ Oluwa, a o gbà a là.
Kà Iṣe Apo 2
Feti si Iṣe Apo 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Iṣe Apo 2:14-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò