Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni. Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé, ‘Ọlọrun sọ pé, “Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn, n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran, àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá. Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí mi sórí àwọn ẹrukunrin mi ati sí orí àwọn ẹrubinrin mi, àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run, ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé; ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀, kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa. Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’
Kà ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:14-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò